Job 24

24
1ẼṢE bi igba-igba kò pamọ lọdọ Olodumare; ti awọn ojulumọ rẹ̀ kò ri ọjọ rẹ̀?
2Nwọn a ṣi àmi àla ilẹ, nwọn a fi agbara ko agbo ẹran lọ, nwọn si bọ́ wọn.
3Nwọn a si dà kẹtẹkẹtẹ alainibaba lọ, nwọn a si gba ọdá-malu opó li ohun ògo.
4Nwọn a bì alaini kuro loju ọ̀na, awọn talaka aiye a sa pamọ́ pọ̀.
5Kiyesi i, bi kẹtẹkẹtẹ igbẹ ninu ijù ni nwọn ijade lọ si iṣẹ wọn; nwọn a tete dide lati wá ohun ọdẹ; ijù pese onjẹ fun wọn ati fun awọn ọmọ wọn.
6Olukuluku a si ṣa ọka onjẹ-ẹran rẹ̀ ninu oko, nwọn a si ká ọgba-ajara enia buburu.
7Nihoho ni nwọn ma sùn laini aṣọ, ti nwọn kò ni ibora ninu otutu.
8Ọwara ojo oke-nla si pa wọn, nwọn si lẹ̀mọ apata nitoriti kò si abo.
9Nwọn ja ọmọ-alainibaba kuro li ẹnu-ọmu, nwọn si gbà ohun ẹ̀ri li ọwọ talaka.
10Nwọn rìn kiri nihoho laili aṣọ, awọn ti ebi npa rẹrù ìdi-ọka.
11Awọn ẹniti nfún ororo ninu agbala wọn, ti nwọn si ntẹ ifunti àjara, ongbẹ si ngbẹ wọn.
12Awọn enia nkerora lati ilu wá, ọkàn awọn ẹniti o gbọgbẹ kigbe soke; sibẹ Ọlọrun kò kiyesi iwère na.
13Awọn li o wà ninu awọn ti o kọ̀ imọlẹ, nwọn kò mọ̀ ipa ọ̀na rẹ̀, bẹni nwọn kò duro nipa ọ̀na rẹ̀.
14Panipani a dide li afẹmọ́jumọ pa talaka ati alaini, ati li oru a di olè.
15Oju àlagbere pẹlu duro de ofefe ọjọ, o ni, Oju ẹnikan kì yio ri mi, o si fi iboju boju rẹ̀.
16Li òkunkun nwọn a runlẹ wọle, ti nwọn ti fi oju sọ fun ara wọn li ọsan, nwọn kò mọ̀ imọlẹ.
17Nitoripe bi oru dudu ni owurọ̀ fun gbogbo wọn; nitoriti nwọn si mọ̀ ibẹru oru dudu.
18O yara lọ bi ẹni loju omi; ifibu ni ipin wọn li aiye, on kò rìn lọ mọ li ọ̀na ọgba-ajara.
19Ọdá ati õru ni imu omi ojo-didi gbẹ, bẹ̃ni isa-okú irun awọn ẹ̀lẹṣẹ.
20Inu ibímọ yio gbagbe rẹ̀, kokoro ni yio ma fi adun jẹun lara rẹ̀, a kì yio ranti rẹ̀ mọ́; bẹ̃ni a o si ṣẹ ìwa-buburu bi ẹni ṣẹ igi.
21Ẹniti o hù ìwa-buburu si agàn ti kò bí ri, ti kò ṣe rere si opó.
22O fi ipá rẹ̀ fà alagbara lọ pẹlu; o dide, kò si ẹniti ẹmi rẹ̀ da loju.
23On si fi ìwa ailewu fun u, ati ninu eyi ni a o si tì i lẹhin, oju rẹ̀ si wà ni ipa-ọna wọn.
24A gbe wọn lekè nigba diẹ, nwọn kọja lọ, a si rẹ̀ wọn silẹ, a si mu wọn kuro li ọ̀na, bi awọn ẹlomiran, a si ke wọn kuro bi ori ṣiri itú ọkà bàbà.
25Njẹ, bi kò ba ri bẹ̃ nisisiyi, tani yio mu mi li eké, ti yio si fi ọ̀rọ mi ṣe alainidi?

Àwon tá yàn lọ́wọ́lọ́wọ́ báyìí:

Job 24: YBCV

Ìsàmì-sí

Pín

Daako

None

Ṣé o fẹ́ fi àwọn ohun pàtàkì pamọ́ sórí gbogbo àwọn ẹ̀rọ rẹ? Wọlé pẹ̀lú àkántì tuntun tàbí wọlé pẹ̀lú àkántì tí tẹ́lẹ̀