Fa ara rẹ sunmọ Ọlọrun, iwọ o si ri alafia; nipa eyinì rere yio wá ba ọ. Emi bẹ̀ ọ, gba ofin lati ẹnu rẹ̀ wá, ki o si tò ọ̀rọ rẹ̀ si aiya rẹ. Bi iwọ ba yipada sọdọ Olodumare, a si gbe ọ ró, bi iwọ ba si mu ẹ̀ṣẹ jina rére kuro ninu agọ rẹ. Ti iwọ ba tẹ wura daradara silẹ lori erupẹ ati wura ófiri labẹ okuta odò. Nigbana ni Olodumare yio jẹ iṣura rẹ, ani yio si jẹ fadaka fun ọ ni ọ̀pọlọpọ. Lotitọ nigbana ni iwọ o ni inu didùn ninu Olodumare, iwọ o si gbe oju rẹ soke sọdọ Ọlọrun. Bi iwọ ba gbadura rẹ sọdọ rẹ̀, yio si gbọ́ tirẹ, iwọ o si san ẹ̀jẹ́ rẹ. Iwọ si gbimọ ohun kan pẹlu, yio si fi idi mulẹ fun ọ; imọlẹ yio si mọ́ sipa ọ̀na rẹ. Nigbati ipa-ọ̀na rẹ ba lọ sisalẹ, nigbana ni iwọ o wipe, Igbesoke mbẹ! Ọlọrun yio si gba onirẹlẹ là! Yio gba ẹniti kì iṣe alaijẹbi là, a o si gbà a nipa mimọ́ ọwọ rẹ.
Kà Job 22
Feti si Job 22
Pín
Fi gbogbo Èyá wéra: Job 22:21-30
Ṣe àfipamọ́ àwọn ẹsẹ, kàá ní aìsìní orí ayélujára, wo àwọn àgékúrú ìkọ́ni, àti díẹ̀ síi!
Ilé
Bíbélì
Àwon ètò
Àwon Fídíò