Job 18

18
1NIGBANA ni Bildadi, ara Ṣua, dahùn o si wipe,
2Nigba wo li ẹnyin o to fi idi ọ̀rọ tì; ẹ rò o, nigbẹhin rẹ̀ li awa o to ma sọ.
3Nitori kili a ṣe nkà wa si bi ẹranko, ti a si nkà wa si bi ẹni ẹ̀gan li oju nyin!
4Iwọ nfa ara rẹ ya pẹrẹpẹrẹ ninu ibinu rẹ, ki a ha kọ̀ aiye silẹ nitori rẹ bi? tabi ki a ṣi apata kuro ni ipo rẹ̀?
5Nitotọ imọlẹ enia buburu li a o pa kuro, ọ̀wọ-iná rẹ̀ kì yio si tan imọlẹ:
6Imọlẹ yio ṣokunkun ninu agọ rẹ̀, fitila rẹ̀ li a o si pa pẹlu rẹ̀.
7Irin ẹsẹ agbara rẹ̀ yio di fifọn, ìmọ on tikararẹ ni yio bi i ṣubu.
8Nipa ẹsẹ on tikararẹ̀ o ti bọ́ sinu àwọn, o si rìn lori okùn didẹ.
9Okùn ẹgẹ́ ni yio mu u ni gigĩsẹ, awọn igara yio si ṣẹgun rẹ̀.
10A dẹkùn silẹ fun u lori ilẹ, a si wà ọ̀fin fun u loju ọ̀na.
11Ẹ̀ru nla yio bà a ni iha gbogbo, yio si le e de ẹsẹ rẹ̀.
12Ailera rẹ̀ yio di pipa fun ebi, iparun yio dide duro si i ni iha rẹ̀.
13Yio jẹ ẹ̀ya ara rẹ̀, akọbi ikú ni yio jẹ agbara rẹ̀ run.
14Eyi ti o ti gbẹkẹle ni a o fàtu kuro ninu agọ rẹ̀, yio si tọ̀ ọba ẹ̀ru nla nì lọ.
15Yio si ma joko ninu agọ rẹ̀ eyi ti kì iṣe tirẹ̀, imi-õrùn li a ọ fún kakiri si ara ile rẹ̀.
16Gbongbo rẹ̀ yio gbẹ nisalẹ, a o si ke ẹ̀ka rẹ̀ kuro loke.
17Iranti rẹ̀ yio parun kuro li aiye, kì yio si orukọ rẹ̀ ni igboro ilu.
18A o si le e lati inu imọlẹ sinu òkunkun, a o si le e kuro li aiye.
19Kì yio ni ọmọ bibikunrin tabi ajọbi-kunrin ninu awọn enia rẹ̀, bẹ̃ni kò si ẹnikan ti o kù ninu agbo ile rẹ̀.
20Ẹnu yio ya awọn iran ti ìwọ-õrùn si igba ọjọ rẹ̀, gẹgẹ bi ẹ̀ru iwariri ti ba awọn iran ti ila-õrùn.
21Nitõtọ iru-bẹ̃ ni ibujoko awọn enia buburu, eyi si ni ipo ẹni ti kò mọ̀ Ọlọrun.

Àwon tá yàn lọ́wọ́lọ́wọ́ báyìí:

Job 18: YBCV

Ìsàmì-sí

Pín

Daako

None

Ṣé o fẹ́ fi àwọn ohun pàtàkì pamọ́ sórí gbogbo àwọn ẹ̀rọ rẹ? Wọlé pẹ̀lú àkántì tuntun tàbí wọlé pẹ̀lú àkántì tí tẹ́lẹ̀