Job 17

17
1EMI mi bajẹ, ọjọ mi parun, isa-okú duro dè mi.
2Nitõtọ! awọn ẹlẹya wà lọdọ mi, oju mi si tẹmọ́ imunibinu wọn.
3Njẹ nisisiyi, fi lelẹ! yàn onigbọwọ fun mi lọdọ rẹ; tani oluwa rẹ̀ ti yio ba mi so ọwọ pọ̀?
4Nitoripe iwọ ti sé wọn laiya kuro ninu oye, nitorina iwọ kì yio gbé wọn leke.
5Ẹniti o fi awọn ọrẹ hàn fun igára, on ni oju awọn ọmọ rẹ̀ yio mu ofo.
6O si sọ mi di ẹni-owe fun awọn enia, niwaju wọn ni mo dabi ẹni itutọ́ si li oju.
7Oju mi ṣú baibai pẹlu nitori ibinujẹ, gbogbo ẹ̀ya ara mi si dabi ojiji.
8Awọn olododo yio yanu si eyi, ẹni alaiṣẹ̀ si binu si awọn àgabagebe.
9Olododo pẹlu yio di ọ̀na rẹ̀ mu, ati ọlọwọ mimọ́ yio ma lera siwaju.
10Ṣugbọn bi o ṣe ti gbogbo nyin, ẹ yipada, ki ẹ si tun bọ̀ nisisiyi, emi kò le ri ọlọgbón kan ninu nyin.
11Ọjọ ti emi ti kọja, iro mi ti fà já, ani iro inu mi.
12A sọ oru di ọ̀san; nwọn ni, imọlẹ sunmọ ibiti òkunkun de.
13Bi mo tilẹ ni ireti, ipo-okú ni ile mi, mo ti tẹ bùsun mi sinu òkunkun.
14Emi ti wi fun idibajẹ pe, Iwọ ni baba mi, ati fun kòkoro pe, Iwọ ni iya mi ati arabinrin mi.
15Ireti mi ha dà nisisiyi? bi o ṣe ti ireti mi ni, tani yio ri i?
16O sọkalẹ lọ sinu ọgbun ipo-okú, nigbati a jumọ simi pọ̀ ninu erupẹ ilẹ.

Àwon tá yàn lọ́wọ́lọ́wọ́ báyìí:

Job 17: YBCV

Ìsàmì-sí

Pín

Daako

None

Ṣé o fẹ́ fi àwọn ohun pàtàkì pamọ́ sórí gbogbo àwọn ẹ̀rọ rẹ? Wọlé pẹ̀lú àkántì tuntun tàbí wọlé pẹ̀lú àkántì tí tẹ́lẹ̀