Job 11:1-20

Job 11:1-20 YBCV

NIGBANA ni Sofari, ara Naama, dahùn o si wipe, A le iṣe ki a má ṣe dahùn si ọ̀pọlọpọ ọ́rọ, a ha si le dare fun ẹniti ẹnu rẹ̃ kún fun ọ̀rọ sisọ? Amọ̀tan rẹ le imu enia pa ẹnu wọn mọ bi? bi iwọ ba yọṣuti si ni, ki ẹnikẹni ki o má si doju tì ọ bi? Nitori iwọ sa ti wipe, ọ̀rọ ẹkọ́ mi mọ́, emi si mọ́ li oju rẹ. Ṣugbọn o ṣe! Ọlọrun iba jẹ sọ̀rọ, ki o si ya ẹnu rẹ̀ si ọ lara. Ki o si fi aṣiri ọgbọ́n hàn ọ pe, o pọ̀ jù oye enia lọ; nitorina mọ̀ pe: Ọlọrun kò bere to bi ẹbi rẹ. Iwọ ha le fi awari ri idi Ọlọrun? iwọ le ri idi Olodumare de pipé rẹ̀? O dabi giga ọrun, kini iwọ le iṣe? o jinlẹ jù ipo-okú lọ, kini iwọ le imọ̀? Ìwọn rẹ̀ gùn jù aiye lọ, o si ni ìbu jù okun lọ. Bi on ba rekọja, ti o si sénà, tabi ti o si ṣe ikojọpọ, njẹ tani yio da a pada kuro? On sa mọ̀ enia asan, o ri ìwa-buburu pẹlu, on kò si ni ṣe lãlã lati ṣà a rò. Enia lasan a sa ma fẹ iṣe ọlọgbọ́n, bi a tilẹ ti bi enia bi ọmọ kẹtẹkẹtẹ. Bi iwọ ba tun ọkàn rẹ ṣe, ti iwọ si nawọ rẹ sọdọ rẹ̀. Bi aiṣedede kan ba mbẹ lọwọ rẹ, mu u kuro si ọ̀na jijin rére, máṣe jẹ ki iwàkiwa kó wà ninu agọ rẹ. Nigbana ni iwọ o gbe oju rẹ soke laini abawọn, ani iwọ o duro ṣinṣin, iwọ kì yio si bẹ̀ru. Nitoripe iwọ o gbagbe òṣi rẹ, iwọ o si ranti rẹ̀ bi omi ti o ti ṣàn kọja lọ. Ọjọ aiye rẹ yio si mọlẹ jù ọsan gangan lọ, bi okunkun tilẹ bò ọ mọlẹ nisisiyi, iwọ o dabi owurọ̀. Iwọ o si wà lailewu, nitoripe ireti wà, ani iwọ o rin ilẹ rẹ wò, iwọ o si simi li alafia. Iwọ o si dubulẹ pẹlu kì yio si sí ẹniti yio dẹ̀ruba ọ, ani ọ̀pọ enia yio ma wá oju-rere rẹ. Ṣugbọn oju eniakenia yio mófo, nwọn kì yio le sala, ireti wọn a si dabi ẹniti o jọwọ ẹmi rẹ̀ lọwọ.