Job 11:1-20

Job 11:1-20 Bibeli Mimọ (YBCV)

NIGBANA ni Sofari, ara Naama, dahùn o si wipe, A le iṣe ki a má ṣe dahùn si ọ̀pọlọpọ ọ́rọ, a ha si le dare fun ẹniti ẹnu rẹ̃ kún fun ọ̀rọ sisọ? Amọ̀tan rẹ le imu enia pa ẹnu wọn mọ bi? bi iwọ ba yọṣuti si ni, ki ẹnikẹni ki o má si doju tì ọ bi? Nitori iwọ sa ti wipe, ọ̀rọ ẹkọ́ mi mọ́, emi si mọ́ li oju rẹ. Ṣugbọn o ṣe! Ọlọrun iba jẹ sọ̀rọ, ki o si ya ẹnu rẹ̀ si ọ lara. Ki o si fi aṣiri ọgbọ́n hàn ọ pe, o pọ̀ jù oye enia lọ; nitorina mọ̀ pe: Ọlọrun kò bere to bi ẹbi rẹ. Iwọ ha le fi awari ri idi Ọlọrun? iwọ le ri idi Olodumare de pipé rẹ̀? O dabi giga ọrun, kini iwọ le iṣe? o jinlẹ jù ipo-okú lọ, kini iwọ le imọ̀? Ìwọn rẹ̀ gùn jù aiye lọ, o si ni ìbu jù okun lọ. Bi on ba rekọja, ti o si sénà, tabi ti o si ṣe ikojọpọ, njẹ tani yio da a pada kuro? On sa mọ̀ enia asan, o ri ìwa-buburu pẹlu, on kò si ni ṣe lãlã lati ṣà a rò. Enia lasan a sa ma fẹ iṣe ọlọgbọ́n, bi a tilẹ ti bi enia bi ọmọ kẹtẹkẹtẹ. Bi iwọ ba tun ọkàn rẹ ṣe, ti iwọ si nawọ rẹ sọdọ rẹ̀. Bi aiṣedede kan ba mbẹ lọwọ rẹ, mu u kuro si ọ̀na jijin rére, máṣe jẹ ki iwàkiwa kó wà ninu agọ rẹ. Nigbana ni iwọ o gbe oju rẹ soke laini abawọn, ani iwọ o duro ṣinṣin, iwọ kì yio si bẹ̀ru. Nitoripe iwọ o gbagbe òṣi rẹ, iwọ o si ranti rẹ̀ bi omi ti o ti ṣàn kọja lọ. Ọjọ aiye rẹ yio si mọlẹ jù ọsan gangan lọ, bi okunkun tilẹ bò ọ mọlẹ nisisiyi, iwọ o dabi owurọ̀. Iwọ o si wà lailewu, nitoripe ireti wà, ani iwọ o rin ilẹ rẹ wò, iwọ o si simi li alafia. Iwọ o si dubulẹ pẹlu kì yio si sí ẹniti yio dẹ̀ruba ọ, ani ọ̀pọ enia yio ma wá oju-rere rẹ. Ṣugbọn oju eniakenia yio mófo, nwọn kì yio le sala, ireti wọn a si dabi ẹniti o jọwọ ẹmi rẹ̀ lọwọ.

Job 11:1-20 Yoruba Bible (YCE)

Sofari ará Naama dáhùn pé, “Ǹjẹ́ ó dára kí eniyan sọ ọpọlọpọ ọ̀rọ̀ kalẹ̀ báyìí kí ó má sì ìdáhùn? Àbí, ṣé ọ̀pọ̀ ọ̀rọ̀ lè mú kí á dá eniyan láre? Ṣé o rò pé ìsọkúsọ rẹ lè pa eniyan lẹ́nu mọ́ ni? Tabi pé bí o bá ń ṣe ẹlẹ́yà ẹnikẹ́ni kò lè dójútì ọ́? Nítorí o sọ pé ẹ̀kọ́ rẹ tọ̀nà, ati pé ẹni mímọ́ ni ọ́ lójú Ọlọrun. Ọlọrun ìbá ya ẹnu rẹ̀, kí ó sọ̀rọ̀ sí ọ. Kì bá jẹ́ fi àṣírí ọgbọ́n hàn ọ́, nítorí ìmọ̀ rẹ̀ pọ̀ lọpọlọpọ. Mọ̀ dájú pé ìyà tí Ọlọrun fi jẹ ọ́ kò to nǹkan lẹ́gbẹ̀ẹ́ ẹ̀ṣẹ̀ rẹ. “Ǹjẹ́ o lè wádìí àwọn ohun ìjìnlẹ̀ nípa Ọlọrun? Tabi kí o tọpinpin Olodumare? Ó ga ju ọ̀run lọ, kí lo lè ṣe sí i? Ó jìn ju isà òkú lọ, kí lo lè mọ̀ nípa rẹ̀? Ó gùn ju ayé lọ, Ó sì fẹ̀ ju òkun lọ. Tí ó bá ń kọjá lọ, tí ó sì ti eniyan mọ́lé, tí ó pe olúwarẹ̀ lẹ́jọ́, ta ló lè yẹ̀ ẹ́ lọ́wọ́ wò? Nítorí ó mọ àwọn eniyan lásán, ṣé bí ó bá rí ẹ̀ṣẹ̀, kí ó má ṣe akiyesi rẹ̀? Ó di ìgbà tí kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ bá bí ọmọ rẹ̀ ní eniyan, kí òmùgọ̀ eniyan tó gbọ́n. “Bí o bá fi ọkàn rẹ sí ohun tí ó tọ́, o óo lè nawọ́ sí i. Bí o bá ń dẹ́ṣẹ̀, má dẹ́ṣẹ̀ mọ́, má sì ṣe jẹ́ kí ìwà burúkú, wà ní ọwọ́ rẹ. Nígbà náà ni o óo tó lè fi ìgboyà gbójú sókè láìlẹ́bi; o óo wà láìléwu, o kò sì ní bẹ̀rù. O óo gbàgbé àwọn ìyọnu rẹ, nígbà tí o bá sì ranti rẹ̀, yóo dàbí ìkún omi tí ó ti wọ́ lọ. Ayé rẹ yóo mọ́lẹ̀ ju ọ̀sán gangan lọ; òkùnkùn rẹ yóo sì dàbí òwúrọ̀. Ọkàn rẹ óo balẹ̀, nítorí pé o ní ìrètí, a óo dáàbò bò ọ́, o óo sì sinmi láìséwu. O óo sùn, láìsí ìdágìrì, ọpọlọpọ eniyan ni wọn óo sì máa wá ojurere rẹ. Àwọn ẹni ibi óo pòfo; gbogbo ọ̀nà tí wọ́n lè gbà sá àsálà ni yóo parẹ́ mọ́ wọn lójú, ikú ni yóo sì jẹ́ ìrètí wọn.”

Job 11:1-20 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní (YCB)

Ìgbà náà ni Sofari, ará Naama, dáhùn, ó sì wí pé: “A ha lè ṣe kí a máa dáhùn sí ọ̀pọ̀lọpọ̀ ọ̀rọ̀? A ha lè fi gbogbo ọ̀rọ̀ wọ̀nyí da ènìyàn láre? Ṣé àmọ̀tán rẹ le mú ènìyàn pa ẹnu wọn mọ́ bí? Ṣé ẹnikẹ́ni kò ní bá ọ wí bí ìwọ bá yọ ṣùtì sí ni? Ìwọ sá à ti wí fún Ọlọ́run pé, ‘ìṣe mi jẹ́ aláìléérí, èmi sì mọ́ ní ojú rẹ.’ Ṣùgbọ́n Ọlọ́run ìbá jẹ́ sọ̀rọ̀, kí ó sì ya ẹnu rẹ̀ sí ọ; Kí ó sì fi àṣírí ọgbọ́n hàn ọ́ pé, ó pọ̀ ju òye ènìyàn lọ; Nítorí náà, mọ̀ pé Ọlọ́run ti gbàgbé àwọn ẹ̀ṣẹ̀ rẹ kan. “Ìwọ ha le ṣe àwárí ohun ìjìnlẹ̀ Ọlọ́run bí? Ìwọ ha le ṣe àwárí ibi tí Olódùmarè dé bi? Ó ga ju àwọn ọ̀run lọ; kí ni ìwọ le è ṣe? Ó jì ju jíjìn isà òkú lọ; kí ni ìwọ le mọ̀? Ìwọ̀n rẹ̀ gùn ju ayé lọ, ó sì ní ibú ju Òkun lọ. “Bí òun bá rékọjá, tí ó sì sé ọnà, tàbí tí ó sì mú ni wá sí ìdájọ́, ǹjẹ́, ta ni ó lè dí i lọ́wọ́? Òun sá à mọ ẹlẹ́tàn ènìyàn; àti pé ṣé bí òun bá rí ohun búburú, ṣé òun kì i fi iyè sí i? Ṣùgbọ́n òmùgọ̀ ènìyàn ki yóò di ọlọ́gbọ́n, bi ko ti rọrùn fún ọmọ kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ igbó láti bí ènìyàn. “Bí ìwọ bá fi ọkàn rẹ fún un, tí ìwọ sì na ọwọ́ rẹ sí ọ̀dọ̀ rẹ̀, Bí ìwọ bá gbé ẹ̀ṣẹ̀ tí ń bẹ ní ọwọ́ rẹ jù sọnù, tí ìwọ kò sì jẹ́ kí aburú gbé nínú àgọ́ rẹ. Nígbà náà ni ìwọ ó gbé ojú rẹ sókè láìní àbàwọ́n, àní ìwọ yóò dúró ṣinṣin, ìwọ kì yóò sì bẹ̀rù, Nítorí pé ìwọ ó gbàgbé ìṣòro rẹ, ìwọ ó sì rántí rẹ̀ bí omi tí ó ti sàn kọjá lọ. Ọjọ́ ayé rẹ yóò sì mọ́lẹ̀ ju ọ̀sán gangan lọ, bí òkùnkùn tilẹ̀ bò ọ́ mọ́lẹ̀ nísinsin yìí, ìwọ ó dàbí òwúrọ̀. Ìwọ ó sì wà láìléwu, nítorí pé ìrètí wà; àní ìwọ ó rin ilé rẹ wò, ìwọ ó sì sinmi ní àlàáfíà. Ìwọ ó sì dùbúlẹ̀ pẹ̀lú, kì yóò sì sí ẹni tí yóò dẹ́rùbà ọ́, àní ènìyàn yóò máa wá ojúrere rẹ. Ṣùgbọ́n ojú ìkà ènìyàn yóò mófo; gbogbo ọ̀nà àbáyọ ni yóò nù wọ́n, ìrètí wọn a sì dàbí ẹni tí ó jọ̀wọ́ ẹ̀mí rẹ̀ lọ́wọ́.”