Joh 9:24-41

Joh 9:24-41 YBCV

Nitorina nwọn pè ọkunrin afọju na lẹ̃keji, nwọn si wi fun u pe, Fi ogo fun Ọlọrun: awa mọ̀ pe ẹlẹṣẹ li ọkunrin yi iṣe. Nitorina o dahùn o si wipe, Bi ẹlẹṣẹ ni, emi kò mọ̀: ohun kan ni mo mọ̀, pe mo ti fọju ri, mo riran nisisiyi. Nitorina nwọn wi fun u pe, Kili o ṣe si ọ? o ti ṣe là ọ loju? O da wọn lohùn wipe, Emi ti sọ fun nyin na, ẹnyin ko si gbọ́: nitori kini ẹnyin ṣe nfẹ tún gbọ́? ẹnyin pẹlu nfẹ ṣe ọmọ-ẹhin rẹ̀ bi? Nwọn si fi i ṣe ẹlẹyà, nwọn si wipe, Iwọ li ọmọ-ẹhin rẹ̀; ṣugbọn ọmọ-ẹhin Mose li awa. Awa mọ̀ pe Ọlọrun ba Mose sọ̀rọ: ṣugbọn bi o ṣe ti eleyi, awa kò mọ̀ ibiti o gbé ti wá. Ọkunrin na dahùn o si wi fun wọn pe, Ohun iyanu sá li eyi, pe, ẹnyin kò mọ̀ ibiti o gbé ti wá, ṣugbọn on sá ti là mi loju. Awa mọ̀ pe, Ọlọrun ki igbọ́ ti ẹlẹṣẹ: ṣugbọn bi ẹnikan ba ṣe olufọkansin si Ọlọrun, ti o ba si nṣe ifẹ rẹ̀, on ni igbọ́ tirẹ̀. Lati igba ti aiye ti ṣẹ̀, a kò ti igbọ́ pe, ẹnikan là oju ẹniti a bí li afọju rí. Ibaṣepe ọkunrin yi ko ti ọdọ Ọlọrun wá, kì ba ti le ṣe ohunkohun. Nwọn si dahùn wi fun u pe, Ninu ẹṣẹ li a bi iwọ patapata, iwọ si nkọ́ wa bi? Nwọn si tì i sode. Jesu gbọ́ pe, nwọn ti tì i sode; nigbati o si ri i, o wipe, Iwọ gbà Ọmọ Ọlọrun gbọ́ bi? On si dahùn wipe, Tani, Oluwa, ki emi ki o le gbà a gbọ́? Jesu wi fun u pe, Iwọ ti ri i, on na si ni ẹniti mba ọ sọ̀rọ yi. O si wipe, Oluwa, mo gbagbọ́, o si wolẹ fun u. Jesu si wipe, Nitori idajọ ni mo ṣe wá si aiye yi, ki awọn ti kò riran, le riran; ati ki awọn ti o riran le di afọju. Ninu awọn Farisi ti o wà lọdọ rẹ̀ gbọ́ nkan wọnyi, nwọn si wi fun u pe, Awa pẹlu fọju bi? Jesu wi fun wọn pe, Ibaṣepe ẹnyin fọju, ẹnyin kì ba ti li ẹ̀ṣẹ: ṣugbọn nisisiyi ẹnyin wipe, Awa riran; nitorina ẹ̀ṣẹ nyin wà sibẹ̀.

Àwọn fídíò fún Joh 9:24-41

YouVersion nlo awọn kuki lati ṣe adani iriri rẹ. Nipa lilo oju opo wẹẹbu wa, o gba lilo awọn kuki wa gẹgẹbi a ti ṣalaye ninu Eto Afihan wa