Nitorina awọn onṣẹ pada tọ̀ awọn olori alufa ati awọn Farisi wá; nwọn si wi fun wọn pe, Ẽṣe ti ẹnyin kò fi mu u wá? Awọn onṣẹ dahùn wipe, Kò si ẹniti o ti isọ̀rọ bi ọkunrin yi ri. Nitorina awọn Farisi da wọn lohùn wipe, A ha tàn ẹnyin jẹ pẹlu bi? O ha si ẹnikan ninu awọn ijoye, tabi awọn Farisi ti o gbà a gbọ́? Ṣugbọn ijọ enia yi, ti kò mọ̀ ofin, di ẹni ifibu. Nikodemu si wi fun wọn pe, (ẹniti o tọ̀ Jesu wá loru, o jẹ ọkan ninu wọn), Ofin wa nṣe idajọ enia ki o to gbọ ti ẹnu rẹ̀, ati ki o to mọ̀ ohun ti o ṣe bi? Nwọn dahùn nwọn si wi fun u pe, Iwọ pẹlu nṣe ara Galili bí? Wá kiri, ki o si wò: nitori kò si woli kan ti o ti Galili dide. Nwọn si lọ olukuluku si ile rẹ̀.
Kà Joh 7
Feti si Joh 7
Pín
Fi gbogbo Èyá wéra: Joh 7:45-53
Ṣe àfipamọ́ àwọn ẹsẹ, kàá ní aìsìní orí ayélujára, wo àwọn àgékúrú ìkọ́ni, àti díẹ̀ síi!
Ilé
Bíbélì
Àwon ètò
Àwon Fídíò