Nigbana li obinrin ara Samaria na wi fun u pe, Ẽti ri ti iwọ ti iṣe Ju, fi mbère ohun mimu lọwọ mi, emi ẹniti iṣe obinrin ara Samaria? nitoriti awọn Ju ki iba awọn ara Samaria da nkan pọ̀. Jesu dahùn, o si wi fun u pe, Ibaṣepe iwọ mọ̀ ẹ̀bun Ọlọrun, ati ẹniti o wi fun ọ pe, Fun mi mu, iwọ iba si ti bère lọwọ rẹ̀, on iba ti fi omi ìye fun ọ. Obinrin na wi fun u pe, Ọgbẹni, iwọ kò ni nkan ti iwọ o fi fà omi, bẹ̃ni kanga na jìn: nibo ni iwọ gbé ti ri omi ìye na? Iwọ pọ̀ju Jakọbu baba wa lọ bí, ẹniti o fun wa ni kanga na, ti on tikararẹ̀ mu ninu rẹ̀, ati awọn ọmọ rẹ̀, ati awọn ẹran rẹ̀? Jesu dahùn, o si wi fun u pe, Ẹnikẹni ti o ba mu ninu omi yi, orùngbẹ yio si tún gbẹ ẹ: Ṣugbọn ẹnikẹni ti o ba mu ninu omi ti emi o fifun u, orùngbẹ kì yio gbẹ ẹ mọ́ lai; ṣugbọn omi ti emi o fifun u yio di kanga omi ninu rẹ̀, ti yio ma sun si ìye ainipẹkun.
Kà Joh 4
Feti si Joh 4
Pín
Fi gbogbo Èyá wéra: Joh 4:9-14
Ṣe àfipamọ́ àwọn ẹsẹ, kàá ní aìsìní orí ayélujára, wo àwọn àgékúrú ìkọ́ni, àti díẹ̀ síi!
Ilé
Bíbélì
Àwon ètò
Àwon Fídíò