Joh 4:11-15

Joh 4:11-15 YBCV

Obinrin na wi fun u pe, Ọgbẹni, iwọ kò ni nkan ti iwọ o fi fà omi, bẹ̃ni kanga na jìn: nibo ni iwọ gbé ti ri omi ìye na? Iwọ pọ̀ju Jakọbu baba wa lọ bí, ẹniti o fun wa ni kanga na, ti on tikararẹ̀ mu ninu rẹ̀, ati awọn ọmọ rẹ̀, ati awọn ẹran rẹ̀? Jesu dahùn, o si wi fun u pe, Ẹnikẹni ti o ba mu ninu omi yi, orùngbẹ yio si tún gbẹ ẹ: Ṣugbọn ẹnikẹni ti o ba mu ninu omi ti emi o fifun u, orùngbẹ kì yio gbẹ ẹ mọ́ lai; ṣugbọn omi ti emi o fifun u yio di kanga omi ninu rẹ̀, ti yio ma sun si ìye ainipẹkun. Obinrin na si wi fun u pe, Ọgbẹni, fun mi li omi yi, ki orùngbẹ ki o màṣe gbẹ mi, ki emi ki o má si wá fà omi nihin.

Àwọn fídíò fún Joh 4:11-15