Joh 20:11-29

Joh 20:11-29 YBCV

Ṣugbọn Maria duro leti ibojì lode, o nsọkun: bi o ti nsọkun, bẹli o bẹ̀rẹ, o si wò inu ibojì. O si kiyesi awọn angẹli meji alaṣọ funfun, nwọn joko, ọkan niha ori, ati ọkan niha ẹsẹ̀, nibiti oku Jesu gbé ti sùn si. Nwọn si wi fun u pe, Obinrin yi, ẽṣe ti iwọ fi nsọkun? O si wi fun wọn pe, Nitoriti nwọn ti gbé Oluwa mi, emi kò si mọ̀ ibiti nwọn gbé tẹ́ ẹ si. Nigbati o si ti wi eyi tan, o yipada, o si ri Jesu duro, kò si mọ̀ pe Jesu ni. Jesu wi fun u pe, Obinrin yi, ẽṣe ti iwọ fi nsọkun? Ta ni iwọ nwá? On ṣebi oluṣọgba ni iṣe, o wi fun u pe, Alàgba, bi iwọ ba ti gbé e kuro nihin, sọ ibiti o gbé tẹ ẹ si fun mi, emi o si gbé e kuro. Jesu wi fun u pe, Maria. O si yipada, o wi fun u pe, Rabboni; eyi ti o jẹ Olukọni. Jesu wi fun u pe, Máṣe fi ọwọ́ kàn mi; nitoriti emi kò ti igòke lọ sọdọ Baba mi: ṣugbọn lọ sọdọ awọn arakunrin mi, si wi fun wọn pe, Emi ngòke lọ sọdọ Baba mi, ati Baba nyin; ati sọdọ Ọlọrun mi, ati Ọlọrun nyin. Maria Magdalene wá, o si sọ fun awọn ọmọ-ẹhin pe, on ti ri Oluwa, ati pe, o si ti sọ nkan wọnyi fun on. Lọjọ kanna, lọjọ ikini ọ̀sẹ nigbati alẹ́ lẹ́, ti a si ti tì ilẹkun ibiti awọn ọmọ-ẹhin gbé pejọ, nitori ìbẹru awọn Ju, bẹni Jesu de, o duro larin, o si wi fun wọn pe, Alafia fun nyin. Nigbati o si ti wi bẹ̃ tan, o fi ọwọ́ ati ìha rẹ̀ hàn wọn. Nitorina li awọn ọmọ-ẹhin yọ̀, nigbati nwọn ri Oluwa. Nitorina Jesu si tún wi fun wọn pe, Alafia fun nyin: gẹgẹ bi Baba ti rán mi, bẹ̃li emi si rán nyin. Nigbati o si ti wi eyi tan, o mí si wọn, o si wi fun wọn pe, Ẹ gbà Ẹmí Mimọ́: Ẹṣẹ ẹnikẹni ti ẹnyin ba fi jì, a fi ji wọn; ẹ̀ṣẹ ẹnikẹni ti ẹnyin ba da duro, a da wọn duro. Ṣugbọn Tomasi, ọkan ninu awọn mejila, ti a npè ni Didimu, kò wà pẹlu wọn nigbati Jesu de. Nitorina awọn ọmọ-ẹhin iyokù wi fun u pe, Awa ti ri Oluwa. Ṣugbọn o wi fun wọn pe, Bikoṣepe mo ba ri àpá iṣo li ọwọ́ rẹ̀ ki emi ki o si fi ika mi si àpá iṣó na, ki emi ki o si fi ọwọ́ mi si ìha rẹ̀, emi kì yio gbagbó. Lẹhin ijọ mẹjọ awọn ọmọ-ẹhin si tún wà ninu ile, ati Tomasi pẹlu wọn: nigbati a si ti tì ilẹkun, Jesu de, o si duro larin, o si wipe, Alafia fun nyin. Nigbana li o wi fun Tomasi pe, Mu ika rẹ wá nihin, ki o si wò ọwọ́ mi; si mu ọwọ́ rẹ wá nihin, ki o si fi si ìha mi: kì iwọ ki o máṣe alaigbagbọ́ mọ́, ṣugbọn jẹ onigbagbọ. Tomasi dahun o si wi fun u pe, Oluwa mi ati Ọlọrun mi! Jesu wi fun u pe, Nitoriti iwọ ri mi ni iwọ ṣe gbagbọ́: alabukun-fun li awọn ti kò ri, ti nwọn si gbagbọ́.

Àwọn fídíò fún Joh 20:11-29

Àwọn ètò kíkà ọ̀fé àti àyọkà tó ní ṣe pẹ̀lú Joh 20:11-29