Joh 16:16-22

Joh 16:16-22 YBCV

Nigba diẹ, ẹnyin kì o si ri mi: ati nigba diẹ ẹ̀wẹ, ẹ ó si ri mi, nitoriti emi nlọ sọdọ Baba. Nitorina omiran ninu awọn ọmọ-ẹhin rẹ̀ mba ara wọn sọ pe, Kili eyi ti o nwi fun wa yi, Nigba diẹ, ẹnyin kì o si ri mi: ati nigba diẹ ẹ̀wẹ, ẹnyin o si ri mi: ati, Nitoriti emi nlọ sọdọ Baba? Nitorina nwọn wipe, Kili eyi ti o wi yi, Nigba diẹ? awa kò mọ̀ ohun ti o wi. Jesu sá ti mọ̀ pe, nwọn nfẹ lati bi on lẽre, o si wi fun wọn pe, Ẹnyin mbi ara nyin lẽre niti eyi ti mo wipe, Nigba diẹ, ẹnyin kì o si ri mi: ati nigba diẹ ẹ̀wẹ, ẹnyin o si ri mi? Lõtọ, lõtọ ni mo wi fun nyin pe, Ẹnyin o ma sọkun ẹ o si ma pohùnrere ẹkún, ṣugbọn awọn araiye yio ma yọ̀: inu nyin yio si bajẹ, ṣugbọn ibinujẹ nyin li yio si di ayọ̀. Nigbati obinrin bá nrọbi, a ni ibinujẹ, nitoriti wakati rẹ̀ de: ṣugbọn nigbati o ba ti bí ọmọ na tan, on kì si iranti irora na mọ́, fun ayọ̀ nitori a bí enia si aiye. Nitorina ẹnyin ni ibinujẹ nisisiyi: ṣugbọn emi o tún ri nyin, ọkàn nyin yio si yọ̀, kò si si ẹniti yio gbà ayọ̀ nyin lọwọ nyin.

Àwọn Fídíò tó Jẹmọ́ ọ