Bi ẹnyin ba fẹran mi, ẹ ó pa ofin mi mọ́.
Emi ó si bère lọwọ Baba, on ó si fun nyin li Olutunu miran, ki o le mã ba nyin gbé titi lailai,
Ani Ẹmí otitọ nì; ẹniti araiye kò le gbà, nitoriti kò ri i, bẹ̃ni kò si mọ̀ ọ: ṣugbọn ẹnyin mọ̀ ọ; nitoriti o mba nyin gbe, yio si wà ninu nyin.
Emi kì o fi nyin silẹ li alaini baba: emi ó tọ̀ nyin wá.
Nigba diẹ si i, aiye ki ó si ri mi mọ́; ṣugbọn ẹnyin ó ri mi: nitoriti emi wà lãye, ẹnyin ó wà lãye pẹlu.
Li ọjọ na li ẹnyin o mọ̀ pe, emi wà ninu Baba mi, ati ẹnyin ninu mi, ati emi ninu nyin.
Ẹniti o ba li ofin mi, ti o ba si npa wọn mọ́, on li ẹniti ọ fẹràn mi: ẹniti o ba si fẹràn mi, a o fẹrán rẹ̀ lati ọdọ Baba mi wá, emi o si fẹràn rẹ̀, emi o si fi ara mi hàn fun u.
Judasi wi fun u pe, (kì iṣe Iskariotu) Oluwa, ẽhatiṣe ti iwọ ó fi ara rẹ hàn fun awa, ti kì yio si ṣe fun araiye?
Jesu dahùn o si wi fun u pe, Bi ẹnikan ba fẹràn mi, yio pa ọ̀rọ mi mọ́: Baba mi yio si fẹran rẹ̀, awa o si tọ̀ ọ wá, a o si ṣe ibugbe wa pẹlu rẹ̀.
Ẹniti kò fẹràn mi ni ko pa ọ̀rọ mi mọ́: ọ̀rọ ti ẹnyin ngbọ́ kì si iṣe ti emi, ṣugbọn ti Baba ti o rán mi.
Nkan wọnyi li emi ti sọ fun nyin, nigbati mo mba nyin gbe.