NJE ki ajọ irekọja ki o to de, nigbati Jesu mọ̀ pe wakati rẹ̀ de tan, ti on ó ti aiye yi kuro lọ sọdọ Baba, fifẹ ti o fẹ awọn tirẹ̀ ti o wà li aiye, o fẹ wọn titi de opin.
Bi nwọn si ti njẹ onjẹ alẹ, ti Èṣu ti fi i si ọkàn Judasi Iskariotu ọmọ Simoni lati fi i hàn;
Ti Jesu si ti mọ̀ pe Baba ti fi ohun gbogbo le on lọwọ, ati pe lọdọ Ọlọrun li on ti wá, on si nlọ sọdọ Ọlọrun;
O dide ni idi onjẹ alẹ, o si fi agbáda rẹ̀ lelẹ̀ li apakan; nigbati o si mu gèle, o di ara rẹ̀ li àmure.
Lẹhinna o bù omi sinu awokòto kan, o si bẹ̀rẹ si ima wẹ̀ ẹsẹ awọn ọmọ-ẹhin rẹ̀, o si nfi gèle ti o fi di àmure nù wọn.
Nigbana li o de ọdọ Simoni Peteru. On si wi fun u pe, Oluwa, iwọ nwẹ̀ mi li ẹsẹ?
Jesu dahùn o si wi fun u pe, Ohun ti emi nṣe iwọ kò mọ̀ nisisiyi; ṣugbọn yio ye ọ nikẹhin.
Peteru wi fun u pe, Iwọ kì yio wẹ̀ mi li ẹsẹ lai. Jesu da a lohùn pe, Bi emi kò bá wẹ̀ ọ, iwọ kò ni ìpin lọdọ mi.
Simoni Peteru wi fun u pe, Oluwa, kì iṣe ẹsẹ mi nikan, ṣugbọn ati ọwọ́ ati ori mi pẹlu.
Jesu wi fun u pe, Ẹniti a ti wẹ̀ kò tun fẹ ju ki a ṣan ẹsẹ rẹ̀, ṣugbọn o mọ́ nibi gbogbo: ẹnyin si mọ́, ṣugbọn kì iṣe gbogbo nyin.
Nitoriti o mọ̀ ẹniti yio fi on hàn; nitorina li o ṣe wipe, Kì iṣe gbogbo nyin li o mọ́.
Nitorina lẹhin ti o wẹ̀ ẹsẹ wọn tan, ti o si ti mu agbáda rẹ̀, ti o tún joko, o wi fun wọn pe, Ẹnyin mọ̀ ohun ti mo ṣe si nyin?
Ẹnyin npè mi li Olukọni ati Oluwa: ẹnyin wi rere; bẹ̃ni mo jẹ.
Njẹ bi emi ti iṣe Oluwa ati Olukọni nyin ba wẹ̀ ẹsẹ nyin, o tọ́ ki ẹnyin pẹlu si mã wẹ̀ ẹsẹ ara nyin.
Nitori mo ti fi apẹ̃rẹ fun nyin, ki ẹnyin ki o le mã ṣe gẹgẹ bi mo ti ṣe si nyin.
Lòtọ, lõtọ ni mo wi fun nyin, Ọmọ-ọdọ kò tobi jù oluwa rẹ̀ lọ; bẹ̃ni ẹniti a rán kò tobi jù ẹniti o rán a lọ.
Bi ẹnyin ba mọ̀ nkan wọnyi, alabukun-fun ni nyin, bi ẹnyin ba nṣe wọn.
Kì iṣe ti gbogbo nyin ni mo nsọ: emi mọ̀ awọn ti mo yàn: ṣugbọn ki iwe-mimọ́ ki o le ṣẹ, Ẹniti mba mi jẹun pọ̀ si gbé gigĩsẹ rẹ̀ si mi.
Lati isisiyi lọ mo sọ fun nyin ki o to de, pe nigbati o ba de, ki ẹnyin ki o le gbagbọ́ pe emi ni.
Lõtọ, lõtọ ni mo wi fun nyin, Ẹniti o ba gbà ẹnikẹni ti mo rán, o gbà mi; ẹniti o ba si gbà mi o gbà ẹniti o rán mi.
Nigbati Jesu ti wi nkan wọnyi tan, ọkàn rẹ̀ daru ninu rẹ̀, o si jẹri, o si wipe, Lõtọ lõtọ ni mo wi fun nyin pe, ọkan ninu nyin yio fi mi hàn.
Awọn ọmọ-ẹhin rẹ̀ nwò ara wọn loju, nwọn nṣiye-meji ti ẹniti o wi.
Njẹ ẹnikan rọ̀gún si àiya Jesu, ọkan ninu awọn ọmọ-ẹhin rẹ̀, ẹniti Jesu fẹràn.
Nitorina ni Simoni Peteru ṣapẹrẹ si i, o si wi fun u pe, Wi fun wa ti ẹniti o nsọ.
Ẹniti o nrọ̀gún li àiya Jesu wi fun u pe, Oluwa, tani iṣe?
Nitorina Jesu dahùn pe, On na ni, ẹniti mo ba fi òkele fun nigbati mo ba fi run. Nigbati o si fi i run tan, o fifun Judasi Iskariotu ọmọ Simoni.
Lẹhin òkele na ni Satani wọ̀ inu rẹ̀ lọ. Nitorina Jesu wi fun u pe, Ohun ti iwọ nṣe nì, yara ṣe e kánkan.
Kò si si ẹnikan nibi tabili ti o mọ̀ idi ohun ti o ṣe sọ eyi fun u.
Nitori awọn miran ninu wọn rò pe, nitori Judasi li o ni àpo, ni Jesu fi wi fun u pe, Rà nkan wọnni ti a kò le ṣe alaini fun ajọ na; tabi ki o le fi nkan fun awọn talakà.
Nigbati o si ti gbà òkele na tan, o jade lojukanna: oru si ni.