Joh 13:1-17

Joh 13:1-17 YBCV

NJE ki ajọ irekọja ki o to de, nigbati Jesu mọ̀ pe wakati rẹ̀ de tan, ti on ó ti aiye yi kuro lọ sọdọ Baba, fifẹ ti o fẹ awọn tirẹ̀ ti o wà li aiye, o fẹ wọn titi de opin. Bi nwọn si ti njẹ onjẹ alẹ, ti Èṣu ti fi i si ọkàn Judasi Iskariotu ọmọ Simoni lati fi i hàn; Ti Jesu si ti mọ̀ pe Baba ti fi ohun gbogbo le on lọwọ, ati pe lọdọ Ọlọrun li on ti wá, on si nlọ sọdọ Ọlọrun; O dide ni idi onjẹ alẹ, o si fi agbáda rẹ̀ lelẹ̀ li apakan; nigbati o si mu gèle, o di ara rẹ̀ li àmure. Lẹhinna o bù omi sinu awokòto kan, o si bẹ̀rẹ si ima wẹ̀ ẹsẹ awọn ọmọ-ẹhin rẹ̀, o si nfi gèle ti o fi di àmure nù wọn. Nigbana li o de ọdọ Simoni Peteru. On si wi fun u pe, Oluwa, iwọ nwẹ̀ mi li ẹsẹ? Jesu dahùn o si wi fun u pe, Ohun ti emi nṣe iwọ kò mọ̀ nisisiyi; ṣugbọn yio ye ọ nikẹhin. Peteru wi fun u pe, Iwọ kì yio wẹ̀ mi li ẹsẹ lai. Jesu da a lohùn pe, Bi emi kò bá wẹ̀ ọ, iwọ kò ni ìpin lọdọ mi. Simoni Peteru wi fun u pe, Oluwa, kì iṣe ẹsẹ mi nikan, ṣugbọn ati ọwọ́ ati ori mi pẹlu. Jesu wi fun u pe, Ẹniti a ti wẹ̀ kò tun fẹ ju ki a ṣan ẹsẹ rẹ̀, ṣugbọn o mọ́ nibi gbogbo: ẹnyin si mọ́, ṣugbọn kì iṣe gbogbo nyin. Nitoriti o mọ̀ ẹniti yio fi on hàn; nitorina li o ṣe wipe, Kì iṣe gbogbo nyin li o mọ́. Nitorina lẹhin ti o wẹ̀ ẹsẹ wọn tan, ti o si ti mu agbáda rẹ̀, ti o tún joko, o wi fun wọn pe, Ẹnyin mọ̀ ohun ti mo ṣe si nyin? Ẹnyin npè mi li Olukọni ati Oluwa: ẹnyin wi rere; bẹ̃ni mo jẹ. Njẹ bi emi ti iṣe Oluwa ati Olukọni nyin ba wẹ̀ ẹsẹ nyin, o tọ́ ki ẹnyin pẹlu si mã wẹ̀ ẹsẹ ara nyin. Nitori mo ti fi apẹ̃rẹ fun nyin, ki ẹnyin ki o le mã ṣe gẹgẹ bi mo ti ṣe si nyin. Lòtọ, lõtọ ni mo wi fun nyin, Ọmọ-ọdọ kò tobi jù oluwa rẹ̀ lọ; bẹ̃ni ẹniti a rán kò tobi jù ẹniti o rán a lọ. Bi ẹnyin ba mọ̀ nkan wọnyi, alabukun-fun ni nyin, bi ẹnyin ba nṣe wọn.

YouVersion nlo awọn kuki lati ṣe adani iriri rẹ. Nipa lilo oju opo wẹẹbu wa, o gba lilo awọn kuki wa gẹgẹbi a ti ṣalaye ninu Eto Afihan wa