Joh 11:39-44

Joh 11:39-44 YBCV

Jesu wipe, Ẹ gbé okuta na kuro. Marta, arabinrin ẹniti o kú na wi fun u pe, Oluwa, o ti nrùn nisisiyi: nitoripe o di ijọ mẹrin ti o ti kú. Jesu wi fun u pe, Emi kò ti wi fun ọ pe, bi iwọ ba gbagbọ́, iwọ o ri ogo Ọlọrun? Nigbana ni nwọn gbé okuta na kuro nibiti a gbe tẹ́ okú na si. Jesu si gbé oju rẹ̀ soke, o si wipe, Baba, mo dupẹ lọwọ rẹ, nitoriti iwọ gbọ́ ti emi. Emi si ti mọ̀ pe, iwọ a ma gbọ́ ti emi nigbagbogbo: ṣugbọn nitori ijọ enia ti o duro yi ni mo ṣe wi i, ki nwọn ki o le gbagbọ́ pe iwọ li o rán mi. Nigbati o si ti wi bẹ̃ tan, o kigbe li ohùn rara pe, Lasaru, jade wá. Ẹniti o kú na si jade wá, ti a fi aṣọ okú dì tọwọ tẹsẹ a si fi gèle dì i loju. Jesu wi fun wọn pe, Ẹ tú u, ẹ si jẹ ki o mã lọ.

Àwọn fídíò fún Joh 11:39-44

Àwọn ètò kíkà ọ̀fé àti àyọkà tó ní ṣe pẹ̀lú Joh 11:39-44