Nitorina Jesu tún wi fun wọn pe, Lõtọ, lõtọ ni mo wi fun nyin, Emi ni ilẹkun awọn agutan.
Olè ati ọlọṣà ni gbogbo awọn ti o ti wá ṣiwaju mi: ṣugbọn awọn agutan kò gbọ́ ti wọn.
Emi ni ilẹkun: bi ẹnikan ba ba ọdọ mi wọle, on li a o gbà là, yio wọle, yio si jade, yio si ri koriko.
Olè kì iwá bikoṣe lati jale, ati lati pa, ati lati parun: emi wá ki nwọn le ni ìye, ani ki nwọn le ni i lọpọlọpọ.
Emi ni oluṣọ-agutan rere: oluṣọ-agutan rere fi ẹmí rẹ̀ lelẹ nitori awọn agutan.
Ṣugbọn alagbaṣe, ti kì iṣe oluṣọ-agutan, ẹniti awọn agutan kì iṣe tirẹ̀, o ri ikõkò mbọ̀, o si fi awọn agutan silẹ, o si sá lọ: ikõkò si mu awọn agutan, o si fọn wọn ká kiri.
Alagbaṣe sá lọ nitoriti iṣe alagbaṣe, kò si náni awọn agutan.
Emi ni oluṣọ-agutan rere, mo si mọ̀ awọn temi, awọn temi si mọ̀ mi.
Gẹgẹ bi Baba ti mọ̀ mi, ti emi si mọ̀ Baba; mo si fi ẹmí mi lelẹ nitori awọn agutan.
Emi si ní awọn agutan miran, ti kì iṣe ti agbo yi: awọn li emi kò le ṣe alaimu wá pẹlu, nwọn ó si gbọ ohùn mi; nwọn o si jẹ agbo kan, oluṣọ-agutan kan.
Nitorina ni Baba mi ṣe fẹran mi, nitoriti mo fi ẹmí mi lelẹ, ki emi ki o le tún gbà a.
Ẹnikan kò gbà a lọwọ mi, ṣugbọn mo fi i lelẹ fun ara mi. Mo li agbara lati fi i lelẹ, mo si li agbara lati tún gbà a. Aṣẹ yi ni mo ti gbà lati ọdọ Baba mi wá.
Nitorina iyapa tun wà larin awọn Ju nitori ọ̀rọ wọnyi.
Ọpọ ninu wọn si wipe, O li ẹmi èṣu, ori rẹ̀ si bajẹ; ẽṣe ti ẹnyin ngbọ̀rọ rẹ̀?
Awọn miran wipe, Wọnyi kì iṣe ọ̀rọ ẹniti o li ẹmi èsu. Ẹmi èsu le là oju awọn afọju bi?
O si jẹ ajọ ọdun iyasimimọ́ ni Jerusalemu, igba otutù ni.
Jesu si nrìn ni tẹmpili, nì ìloro Solomoni.
Nitorina awọn Ju wá duro yi i ká, nwọn si wi fun u pe, Iwọ ó ti mu wa ṣe iyemeji pẹ to? Bi iwọ ni iṣe Kristi na, wi fun wa gbangba.
Jesu da wọn lohùn wipe, Emi ti wi fun nyin, ẹnyin kò si gbagbọ́; iṣẹ ti emi nṣe li orukọ Baba mi, awọn ni njẹri mi.
Ṣugbọn ẹnyin kò gbagbọ́, nitori ẹnyin kò si ninu awọn agutan mi, gẹgẹ bi mo ti wi fun nyin.
Awọn agutan mi ngbọ ohùn mi, emi si mọ̀ wọn, nwọn a si ma tọ̀ mi lẹhin:
Emi si fun wọn ni ìye ainipẹkun; nwọn kì o si ṣegbé lailai, kò si si ẹniti o le já wọn kuro li ọwọ́ mi.
Baba mi, ẹniti o fi wọn fun mi, pọ̀ ju gbogbo wọn lọ; kò si si ẹniti o le já wọn kuro li ọwọ́ Baba mi.
Ọ̀kan li emi ati Baba mi jasi.