Jer 49
49
Ìdájọ́ OLUWA Lórí Amoni
1SI awọn ọmọ Ammoni. Bayi li Oluwa wi; Israeli kò ha ni awọn ọmọkunrin? kò ha ni arole bi? nitori kini Malkomu ṣe jogun Gadi, ti awọn enia rẹ̀ si joko ni ilu rẹ̀?
2Nitorina, wò o, ọjọ mbọ̀, li Oluwa wi, ti emi o mu ki a gbọ́ idagiri ogun ni Rabba ti awọn ọmọ Ammoni: yio si di okiti ahoro, a o si fi iná sun awọn ọmọbinrin rẹ̀; nigbana ni Israeli yio jẹ arole awọn ti o ti jẹ arole rẹ̀, li Oluwa wi.
3Hu, iwọ Heṣboni! nitori a fi Ai ṣe ijẹ: kigbe, ẹnyin ọmọbinrin Rabba! ẹ di aṣọ-ọ̀fọ mọra, ẹ pohunrere, ki ẹ si sare soke-sodo lãrin ọgba! nitori Malkomu yio jumọ lọ si igbekun, awọn alufa rẹ̀ ati awọn ijoye rẹ̀.
4Ẽṣe ti iwọ fi nṣogo ninu afonifoji, afonifoji rẹ nṣan lọ, iwọ ọmọbinrin ti o gbẹkẹle iṣura rẹ, pe, tani yio tọ̀ mi wá?
5Wò o, emi o mu ẹ̀ru wá sori rẹ, li Oluwa Ọlọrun awọn ọmọ-ogun wi, lati ọdọ gbogbo awọn wọnni ti o wà yi ọ kakiri; a o si le nyin, olukuluku enia tàra niwaju rẹ̀; ẹnikan kì o si kó awọn ti nsalọ jọ.
6Ati nikẹhin emi o tun mu igbekun awọn ọmọ Ammoni pada, li Oluwa wi.
Ìdájọ́ OLUWA lórí Edomu
7Si Edomu. Bayi li Oluwa awọn ọmọ-ogun wi; Kò ha si ọgbọ́n mọ ni Temani? a ha ke imọran kuro lọdọ oloye? ọgbọ́n wọn ha danu bi?
8Ẹ sa, ẹ yipada, ẹ ṣe ibi jijin lati ma gbe ẹnyin olugbe Dedani; nitori emi o mu wahala Esau wá sori rẹ̀, àkoko ti emi o bẹ̀ ẹ wò.
9Bi awọn aka-eso ba tọ̀ ọ wá, nwọn kì o ha kù ẽṣẹ́ eso ajara silẹ? bi awọn ole ba wá li oru, nwọn kì o ha parun titi yio fi tẹ́ wọn lọrùn.
10Nitori emi ti tú Esau ni ihoho, emi ti fi ibi ikọkọ rẹ̀ han, on kì o si le fi ara rẹ̀ pamọ; iru-ọmọ rẹ̀ di ijẹ, ati awọn arakunrin rẹ̀, ati awọn aladugbo rẹ̀, nwọn kò sí mọ́.
11Fi awọn ọmọ alainibaba rẹ silẹ, emi o si pa wọn mọ lãye; ati ki awọn opó rẹ ki o gbẹkẹle mi.
12Nitori bayi li Oluwa wi; Wò o, awọn ẹniti kò jẹbi, lati mu ninu ago, ni yio mu u lõtọ: iwọ o ha si lọ li alaijiya? iwọ kì yio lọ li alaijiya, nitori lõtọ iwọ o mu u.
13Nitori emi ti fi ara mi bura, li Oluwa wi pe: Bosra yio di ahoro, ẹ̀gan, idahoro, ati egún; ati gbogbo ilu rẹ̀ ni yio di ahoro lailai.
14Ni gbigbọ́ emi ti gbọ́ iró lati ọdọ Oluwa wá, a si ran ikọ̀ si awọn orilẹ-ède pe, ẹ kó ara nyin jọ, ẹ wá sori rẹ̀, ẹ si dide lati jagun.
15Nitori, wò o, emi o ṣe ọ ni ẹni-kekere lãrin awọn orilẹ-ède, ẹni-ẹgan lãrin awọn enia.
16Ibanilẹ̀ru rẹ ti tan ọ jẹ, igberaga ọkàn rẹ, nitori iwọ ngbe palapala okuta, ti o joko li ori oke, bi iwọ tilẹ kọ́ itẹ́ rẹ ga gẹgẹ bi idì, sibẹ emi o mu ọ sọkalẹ lati ibẹ wá, li Oluwa wi.
17Edomu yio si di ahoro: olukuluku ẹniti o ba rekọja rẹ̀, yio dãmu, yio si rẹrin si gbogbo ipọnju rẹ̀.
18Gẹgẹ bi ni ibiṣubu Sodomu ati Gomorra ati awọn aladugbo rẹ̀, li Oluwa wi; ẹnikan kì yio gbe ibẹ mọ, bẹ̃ni ọmọ enia kan kì yio ṣatipo ninu rẹ̀.
19Wò o, yio goke wá bi kiniun lati igberaga Jordani si ibugbe okuta; nitori lojiji ni emi o lé wọn jade kuro nibẹ, ati tani ayanfẹ na ti emi o yàn sori rẹ̀, nitori tani dabi emi, tani yio si pè mi ṣe ẹlẹri? ati tani oluṣọ-agutan na, ti yio le duro niwaju mi?
20Nitorina gbọ́ ìmọ Oluwa ti o ti gbà si Edomu; ati èro rẹ̀ ti o ti gba si awọn olugbe Temani pe, Lõtọ awọn ẹniti o kere julọ ninu agbo-ẹran yio wọ́ wọn kiri, lõtọ nwọn o sọ buka wọn di ahoro lori wọn.
21Ilẹ o mì nipa ariwo iṣubu wọn, ariwo! a gbọ́ ohùn igbe rẹ̀ li Okun-pupa.
22Wò o, yio goke wá yio si fò gẹgẹ bi idì, yio si nà iyẹ rẹ̀ sori Bosra: ati li ọjọ na ni ọkàn awọn alagbara ọkunrin Edomu yio dabi ọkàn obinrin ni irọbi.
Ìdájọ́ OLUWA lórí Damasku
23Si Damasku. Oju tì Hamati, ati Arpadi: nitori nwọn ti gbọ́ ìhin buburu: aiya ja wọn; idãmu wà lẹba okun; nwọn kò le ri isimi.
24Damasku di alailera, o yi ara rẹ̀ pada lati sa, iwarìri si dì i mu: ẹ̀dun ati irora ti dì i mu, gẹgẹ bi obinrin ti nrọbi.
25Bawo ni a kò ṣe fi ilu iyìn silẹ, ilu ayọ̀ mi!
26Nitorina awọn ọdọmọkunrin rẹ̀ yio ṣubu ni ita rẹ̀, ati gbogbo awọn ọkunrin ogun ni a o ke kuro li ọjọ na, li Oluwa awọn ọmọ-ogun wi.
27Emi o si da iná ni odi Damasku, yio si jo ãfin Benhadadi run.
A Óo Rẹ Moabu sílẹ̀
28Si Kedari, ati si ijọba Hasori, ti Nebukadnessari ọba Babeli, kó: Bayi li Oluwa wi; Dide, goke lọ si Kedari, ki ẹ si pa awọn ọkunrin ìla-õrùn run.
29Agọ wọn ati agbo-ẹran wọn ni nwọn o kó lọ: nwọn o mu aṣọ agọ wọn fun ara wọn, ati gbogbo ohun-èlo wọn, ati ibakasiẹ wọn; nwọn o si kigbe sori wọn pe, Ẹ̀ru yikakiri!
30Sa, yara salọ, fi ara pamọ si ibi jijìn, ẹnyin olugbe Hasori, li Oluwa wi; nitori Nebukadnessari ọba Babeli, ti gbìmọ kan si nyin, o si ti gba èro kan si nyin.
31Dide, goke lọ sọdọ orilẹ-ède kan ti o wà ni irọra, ti o ngbe li ailewu, li Oluwa wi, ti kò ni ilẹkun ẹnu-bode tabi ikere; ti ngbe fun ara rẹ̀.
32Ibakasiẹ wọn yio si di ikogun, ati ọ̀pọlọpọ ẹran-ọ̀sin wọn yio di ijẹ: emi o si tú awọn ti nda òṣu ka si gbogbo ọ̀na afẹfẹ; emi o si mu wahala wọn de lati iha gbogbo, li Oluwa wi.
33Hasori yio di ibugbe fun ọ̀wawa, ahoro titi lai: kì o si ẹnikan ti yio joko nibẹ, bẹ̃ni ọmọ enia kan kì yio ṣatipo ninu rẹ̀.
Ìdájọ́ OLUWA lórí Elamu
34Ọ̀rọ Oluwa ti o tọ Jeremiah, woli, wá si Elamu, ni ibẹrẹ ijọba Sedekiah, ọba Juda, wipe:
35Bayi li Oluwa awọn ọmọ-ogun wi; Wò o, emi o ṣẹ́ ọrun Elamu, ti iṣe olori agbara wọn.
36Ati sori Elamu ni emi o mu afẹfẹ mẹrin lati igun mẹrẹrin ọrun wá, emi o si tú wọn ka si gbogbo ọ̀na afẹfẹ wọnni, kì o si sí orilẹ-ède kan, nibiti awọn ãsá Elamu kì yio de.
37Nitori emi o mu Elamu warìri niwaju awọn ọta wọn, ati niwaju awọn ti nwá ẹmi wọn: emi o si mu ibi wá sori wọn, ani ibinu gbigbona mi, li Oluwa wi; emi o si rán idà tẹle wọn, titi emi o fi run wọn.
38Emi o si gbe itẹ mi kalẹ ni Elamu, emi o si pa ọba ati awọn ijoye run kuro nibẹ, li Oluwa wi.
39Ṣugbọn yio si ṣe, ni ikẹhin ọjọ, emi o tun mu igbèkun Elamu pada, li Oluwa wi.
Àwon tá yàn lọ́wọ́lọ́wọ́ báyìí:
Jer 49: YBCV
Ìsàmì-sí
Pín
Daako
Ṣé o fẹ́ fi àwọn ohun pàtàkì pamọ́ sórí gbogbo àwọn ẹ̀rọ rẹ? Wọlé pẹ̀lú àkántì tuntun tàbí wọlé pẹ̀lú àkántì tí tẹ́lẹ̀
Yoruba Bible Crowther Version © The Bible Society of Nigeria, 2012.