Jer 40
40
Jeremiah Ń Gbé Ọ̀dọ̀ Gedalaya
1Ọ̀RỌ ti o tọ̀ Jeremiah wá lati ọdọ Oluwa, lẹhin ti Nebusaradani, balogun iṣọ, ti ranṣẹ pè e lati Rama. Nitori nigbati o mu u, a fi ẹwọn dè e lãrin gbogbo awọn igbekun Jerusalemu ati Juda, ti a kó ni ìgbekun lọ si Babeli.
2Balogun iṣọ si mu Jeremiah, o si wi fun u pe, Oluwa, Ọlọrun rẹ, ti sọ ibi yi si ilu yi.
3Oluwa si ti mu u wá, o si ṣe gẹgẹ bi o ti wi: nitoripe ẹnyin ti ṣẹ̀ si Oluwa, ẹ kò si gbọ́ ohùn rẹ̀, nitorina ni nkan yi ṣe de ba nyin.
4Njẹ nisisiyi, wò o, mo tú ọ silẹ li oni kuro ninu ẹ̀wọn ti o wà li ọwọ rẹ: bi o ba dara li oju rẹ lati ba mi lọ si Babeli, kalọ, emi o boju to ọ: ṣugbọn bi kò ba dara li oju rẹ lati ba mi lọ si Babeli, jọwọ rẹ̀; wò o, gbogbo ilẹ li o wà niwaju rẹ, ibi ti o ba dara ti o ba si tọ li oju rẹ lati lọ, lọ sibẹ.
5Bi bẹ̃kọ, pada tọ̀ Gedaliah, ọmọ Ahikamu, ọmọ Ṣafani, ẹniti ọba Babeli ti fi jẹ bãlẹ lori ilu Juda, ki o si mã ba a gbe lãrin ọpọ enia, tabi ibikibi ti o ba tọ li oju rẹ, lati lọ, lọ sibẹ̀. Balogun iṣọ si fun u li onjẹ ati ẹbun; o si jọ́wọ́ rẹ̀ lọwọ.
6Jeremiah si lọ sọdọ Gedaliah, ọmọ Ahikamu, ni Mispa; o si mba a gbe lãrin awọn enia, ti o kù ni ilẹ na.
Gedalaya, Gomina Juda
7Njẹ nigbati gbogbo awọn olori ogun, ti o wà li oko, awọn ati awọn ọkunrin wọn, gbọ́ pe ọba Babeli ti fi Gedaliah, ọmọ Ahikamu, jẹ bãlẹ ni ilẹ na, o si ti fi awọn ọkunrin fun u, ati awọn obinrin, ati awọn ọmọde, ati ninu awọn talaka ilẹ na, ninu awọn ti a kò kó lọ ni igbekun si Babeli.
8Nwọn tọ̀ Gedaliah wá ni Mispa, ani Iṣmaeli, ọmọ Netaniah, ati Johanani, ati Jonatani, awọn ọmọ Karea, ati Seraiah, ọmọ Tanhumeti, ati awọn ọmọ Efai, ara Netofa, ati Jesaniah, ọmọ ara Maaka, awọn ati awọn ọkunrin wọn,
9Gedaliah, ọmọ Ahikamu, ọmọ Ṣafani, si bura fun wọn ati fun awọn ọkunrin wọn, wipe: Ẹ má bẹ̀ru lati sìn awọn ara Kaldea: ẹ gbe ilẹ̀ na, ki ẹ si mã sin ọba Babeli, yio si dara fun nyin.
10Bi o ṣe ti emi, wò o, emi o ma gbe Mispa, lati sìn awọn ara Kaldea, ti yio tọ wa wá; ṣugbọn ẹnyin ẹ kó ọti-waini jọ, ati eso-igi, ati ororo, ki ẹ si fi sinu ohun-elo nyin, ki ẹ si gbe inu ilu nyin ti ẹnyin ti gbà.
11Pẹlupẹlu gbogbo awọn ara Juda, ti o wà ni Moabu, ati lãrin awọn ọmọ Ammoni, ati ni Edomu, ati awọn ti o wà ni gbogbo ilẹ wọnni gbọ́ pe, ọba Babeli ti fi iyokù silẹ fun Juda, ati pe o ti fi Gedaliah, ọmọ Ahikamu, ọmọ Ṣafani, ṣolori wọn;
12Gbogbo awọn ara Juda si pada lati ibi gbogbo wá ni ibi ti a ti lé wọn si, nwọn si wá si ilẹ Juda sọdọ Gedaliah si Mispa, nwọn si kó ọti-waini ati eso igi jọ pupọpupọ.
Wọ́n Pa Gedalaya
13Ṣugbọn Johanani, ọmọ Karea, ati gbogbo awọn olori ogun ti o wà li oko, tọ̀ Gedaliah wá si Mispa.
14Nwọn si wi fun u pe, Iwọ ha mọ̀ dajudaju pe: Baalisi, ọba awọn ọmọ Ammoni, ti ran Iṣmaeli, ọmọ Netaniah, lati pa ọ? Ṣugbọn Gedaliah, ọmọ Ahikamu, kò gbà wọn gbọ́.
15Nigbana ni Johanani, ọmọ Karea, si sọ nikọkọ fun Gedaliah ni Mispa pe, Jẹ ki emi lọ, mo bẹ ọ, emi o si pa Iṣmaeli, ọmọ Netaniah, ẹnikan kì yio si mọ̀: Ẽṣe ti on o fi pa ọ, ti gbogbo awọn ara Juda ti a kojọ tì ọ, yio tuka, ati iyokù Juda yio ṣegbe?
16Ṣugbọn Gedaliah, ọmọ Ahikamu, sọ fun Johanani, ọmọ Karea pe, Iwọ kò gbọdọ ṣe nkan yi, nitori eke ni iwọ ṣe mọ Iṣmaeli.
Àwon tá yàn lọ́wọ́lọ́wọ́ báyìí:
Jer 40: YBCV
Ìsàmì-sí
Pín
Daako
Ṣé o fẹ́ fi àwọn ohun pàtàkì pamọ́ sórí gbogbo àwọn ẹ̀rọ rẹ? Wọlé pẹ̀lú àkántì tuntun tàbí wọlé pẹ̀lú àkántì tí tẹ́lẹ̀
Yoruba Bible Crowther Version © The Bible Society of Nigeria, 2012.