Jer 39
39
Ìṣubú Jerusalẹmu
1O si ṣe, nigbati a kó Jerusalemu (li ọdun kẹsan Sedekiah, ọba Juda, li oṣu kẹwa ni Nebukadnessari, ọba Babeli, ati gbogbo ogun rẹ̀ wá si Jerusalemu, nwọn si dó tì i.
2Ati li ọdun kọkanla Sedekiah, li oṣu kẹrin, li ọjọ keṣan oṣu li a fọ ilu na.)
3Gbogbo awọn ijoye ọba Babeli si wọle, nwọn si joko li ẹnu-bode ãrin, ani Nergali-Ṣareseri, Samgari-nebo, Sarsikimu, olori iwẹfa, Nergali-Ṣareseri, olori amoye, pẹlu gbogbo awọn ijoye ọba Babeli iyokù.
4O si ṣe, nigbati Sedekiah, ọba Juda, ati gbogbo awọn ologun ri wọn, nigbana ni nwọn sá, nwọn si jade kuro ni ilu li oru, nwọn gba ọ̀na ọgbà ọba ati ẹnu-bode lãrin odi mejeji, nwọn si jade lọ li ọ̀na pẹtẹlẹ.
5Ṣugbọn ogun awọn ara Kaldea lepa wọn, nwọn si ba Sedekiah, ọba, ni pẹtẹlẹ Jeriko; nigbati nwọn si mu u, nwọn mu u goke wá sọdọ Nebukadnessari, ọba Babeli, ni Ribla ni ilẹ Hamati, nibiti o sọ̀rọ idajọ lori rẹ̀.
6Nigbana ni ọba Babeli pa awọn ọmọ Sedekiah ni Ribla, niwaju rẹ̀; ọba Babeli si pa gbogbo awọn ọlọla Juda pẹlu.
7Pẹlupẹlu o fọ Sedekiah li oju, o si fi ẹ̀wọn dè e, lati mu u lọ si Babeli.
8Awọn ara Kaldea si fi ile ọba ati ile awọn enia joná, nwọn si wó odi Jerusalemu lulẹ.
9Nebusaradani, balogun iṣọ, si kó iyokù awọn enia ti o kù ni ilu ni igbekun lọ si Babeli, pẹlu awọn ti o ti ya lọ, ti o ya sọdọ rẹ̀, pẹlu awọn enia iyokù ti o kù.
10Ṣugbọn Nebusaradani, balogun iṣọ, si mu diẹ ninu awọn enia, ani awọn talaka ti kò ni nkan rara, joko ni ilẹ Juda, o si fi ọgba-àjara ati oko fun wọn li àkoko na.
Wọ́n Dá Jeremiah Sílẹ̀
11Nebukadnessari, ọba Babeli, si paṣẹ fun Nebusaradani, balogun iṣọ, niti Jeremiah, wipe,
12Mu u, ki o si bojuto o, má si ṣe e ni ibi kan; ṣugbọn gẹgẹ bi on ba ti sọ fun ọ, bẹ̃ni ki iwọ ki o ṣe fun u.
13Bẹ̃ni Nebusaradani, balogun iṣọ, ati Nebuṣaṣbani, olori iwẹfa, ati Nergali Ṣareseri, olori amoye, ati gbogbo ijoye ọba Babeli, si ranṣẹ,
14Ani nwọn ranṣẹ nwọn si mu Jeremiah jade ni àgbala ile-tubu, nwọn si fi fun Gedaliah, ọmọ Ahikamu, ọmọ Ṣafani, pe ki o mu u lọ si ile: bẹ̃ni o ngbe ãrin awọn enia.
Ìrètí Wà fún Ebedmeleki
15Ọrọ Oluwa si tọ̀ Jeremiah wá, nigbati a se e mọ ninu àgbala ile-túbu, wipe,
16Lọ, ki o si sọ fun Ebedmeleki, ara Etiopia, wipe: Bayi li Oluwa awọn ọmọ-ogun, Ọlọrun Israeli wi pe, wò o, emi o mu ọ̀rọ mi wá sori ilu yi fun ibi, kì isi ṣe fun rere; nwọn o si ṣẹ niwaju rẹ li ọjọ na.
17Ṣugbọn emi o gbà ọ li ọjọ na, li Oluwa wi: a kì o si fi ọ le ọwọ awọn enia na ti iwọ bẹ̀ru.
18Nitori emi o gbà ọ là nitõtọ, iwọ kì o si ti ipa idà ṣubu, ṣugbọn ẹ̀mi rẹ yio jẹ bi ikogun fun ọ: nitoripe iwọ ti gbẹkẹ rẹ le mi, li Oluwa wi.
Àwon tá yàn lọ́wọ́lọ́wọ́ báyìí:
Jer 39: YBCV
Ìsàmì-sí
Pín
Daako
Ṣé o fẹ́ fi àwọn ohun pàtàkì pamọ́ sórí gbogbo àwọn ẹ̀rọ rẹ? Wọlé pẹ̀lú àkántì tuntun tàbí wọlé pẹ̀lú àkántì tí tẹ́lẹ̀
Yoruba Bible Crowther Version © The Bible Society of Nigeria, 2012.