Jer 29:4-7

Jer 29:4-7 YBCV

Bayi li Oluwa awọn ọmọ-ogun, Ọlọrun Israeli, wi fun gbogbo awọn ti a kó ni igbekun lọ, ti emi mu ki a kó lọ lati Jerusalemu si Babeli; Ẹ kọ́ ile ki ẹ si ma gbe inu wọn; ẹ gbìn ọgba, ki ẹ si mã jẹ eso wọn; Ẹ fẹ́ aya, ki ẹ si bi ọmọkunrin ati ọmọbinrin; ki ẹ si fẹ́ aya fun awọn ọmọ nyin, ẹ si fi awọn ọmọbinrin nyin fun ọkọ, ki nwọn ki o le mã bi ọmọkunrin ati ọmọbinrin; ki ẹ le mã pọ si i nibẹ, ki ẹ má si dínkù. Ki ẹ si mã wá alafia ilu na, nibiti emi ti mu ki a kó nyin lọ ni igbekun, ẹ si mã gbadura si Oluwa fun u: nitori ninu alafia rẹ̀ li ẹnyin o ni alafia.