Ọ̀RỌ ti o tọ̀ Jeremiah wá nitori gbogbo enia Juda, li ọdun kẹrin Jehoiakimu, ọmọ Josiah, ọbà Juda, ti iṣe ọdun ikini Nebukadnessari, ọba Babeli.
Eyi ti Jeremiah, woli, sọ fun gbogbo enia Juda, ati fun awọn olugbe Jerusalemu wipe:
Lati ọdun kẹtala Josiah, ọmọ Amoni, ọba Juda, titi di oni-oloni, eyini ni, ọdun kẹtalelogun, ọ̀rọ Oluwa ti tọ mi wá, emi si ti sọ fun nyin, emi ndide ni kutukutu, emi nsọ, ṣugbọn ẹnyin kò feti si i.
Oluwa si ti rán gbogbo awọn iranṣẹ rẹ̀, awọn woli si nyin, o ndide ni kutukutu lati rán wọn, ṣugbọn ẹnyin kò feti si i, bẹ̃ni ẹnyin kò tẹ eti nyin silẹ lati gbọ́.
Wipe, ẹ sa yipada, olukuluku kuro ni ọ̀na buburu rẹ̀, ati kuro ni buburu iṣe nyin, ẹnyin o si gbe ilẹ ti Oluwa ti fi fun nyin, ati fun awọn baba nyin lai ati lailai.
Ki ẹ má si tọ̀ ọlọrun miran lẹhin lati ma sìn wọn, ati lati ma foribalẹ fun wọn, ki ẹ má si ṣe fi iṣẹ ọwọ nyin mu mi binu, emi kì yio si ṣe nyin ni ibi.
Ṣugbọn ẹnyin kò gbọ́ temi, li Oluwa wi, ki ẹnyin le fi iṣẹ ọwọ nyin mu mi binu si ibi ara nyin.
Nitorina, bayi li Oluwa awọn ọmọ-ogun wi: nitori ti ẹnyin kò gbọ́ ọ̀rọ mi.
Sa wò o, emi o ranṣẹ, emi o si mu gbogbo idile orilẹ-ède ariwa wá, li Oluwa wi, emi o si ranṣẹ si Nebukadnessari, ọba Babeli, ọmọ-ọdọ mi, emi o si mu wọn wá si ilẹ yi, ati olugbe rẹ̀, ati si gbogbo awọn orilẹ-ède yikakiri, emi o si pa wọn patapata, emi o si sọ wọn di iyanu ati iyọṣuti si, ati ahoro ainipẹkun.
Pẹlupẹlu emi o mu ohùn inudidùn, ati ohùn ayọ, ohùn ọkọ-iyawo, ati ohùn iyawo, iro okuta ọlọ, ati imọlẹ fitila kuro lọdọ wọn.
Gbogbo ilẹ yi yio si di iparun ati ahoro: orilẹ-ède wọnyi yio si sìn ọba Babeli li ãdọrin ọdun.
Yio si ṣe, nigbati ãdọrin ọdun ba pari tan, li emi o bẹ̀ ọba Babeli, ati orilẹ-ède na, ati ilẹ awọn ara Kaldea wò, nitori ẹ̀ṣẹ wọn; li Oluwa wi, emi o si sọ ọ di ahoro titi lai.
Emi o si mu gbogbo ọ̀rọ mi wá sori ilẹ na, ti mo ti sọ si i: ani gbogbo eyiti a ti kọ sinu iwe yi, eyiti Jeremiah ti sọtẹlẹ si gbogbo orilẹ-ède.
Nitoriti awọn wọnyi pẹlu yio mu ki orilẹ-ède pupọ, ati awọn ọba nla sìn wọn: emi o san a fun wọn gẹgẹ bi iṣe wọn ati pẹlu gẹgẹ bi iṣẹ ọwọ wọn.