Jer 23

23
Ìrètí Ọjọ́ Iwájú
1EGBE ni fun awọn oluṣọ-agutan, ti nmu agbo-ẹran mi ṣìna, ti o si ntú wọn ka, li Oluwa wi.
2Nitorina bayi li Oluwa Ọlọrun Israeli, wi si oluṣọ-agutan wọnni, ti nṣọ enia mi; Ẹnyin tú agbo-ẹran mi ká, ẹ le wọn junù, ẹnyin kò si bẹ̀ wọn wò, sa wò o, emi o bẹ̀ nyin wò nitori buburu iṣe nyin, li Oluwa wi.
3Emi o si kó iyokù agbo-ẹran mi jọ lati inu gbogbo ilẹ, ti mo ti le wọn si, emi o si mu wọn pada wá sinu pápá oko wọn, nwọn o bi si i, nwọn o si rẹ̀ si i.
4Emi o gbe oluṣọ-agutan dide fun wọn, ti yio bọ́ wọn: nwọn kì yio bẹ̀ru mọ́, tabi nwọn kì yio si dãmu, bẹ̃li ọkan ninu wọn kì yio si sọnu, li Oluwa wi.
5Sa wò o, ọjọ mbọ, li Oluwa wi, ti emi o gbe Ẹka ododo soke fun Dafidi, yio si jẹ Ọba, yio si ṣe rere, yio si ṣe idajọ ati ododo ni ilẹ na.
6Li ọjọ rẹ̀ ni a o gba Juda là, Israeli yio si ma gbe li ailewu, ati eyi li orukọ ti a o ma pè e: OLUWA ODODO WA.
7Nitorina, sa wò o, ọjọ mbọ̀, li Oluwa wi, ti nwọn kì yio tun wipe, Oluwa mbẹ, ti o mu awọn ọmọ Israeli jade kuro ni ilẹ Egipti:
8Ṣugbọn pe, Oluwa mbẹ, ti o mu iru-ọmọ ile Israeli wá, ti o si tọ́ wọn lati ilu ariwa wá, ati lati ilu wọnni nibi ti mo ti lé wọn si, nwọn o si gbe inu ilẹ wọn.
Iṣẹ́ tí Jeremiah Jẹ́ nípa Àwọn Wolii
9Si awọn woli. Ọkàn mi ti bajẹ ninu mi, gbogbo egungun mi mì; emi dabi ọmuti, ati ọkunrin ti ọti-waini ti bori rẹ̀ niwaju Oluwa, ati niwaju ọ̀rọ ìwa-mimọ́ rẹ̀.
10Nitori ilẹ na kún fun awọn panṣaga; ilẹ na nṣọ̀fọ, nitori egún, pápá oko aginju gbẹ: irìn wọn di buburu, agbara wọn kò si to.
11Nitori, ati woli ati alufa, nwọn bajẹ; pẹlupẹlu ninu ile mi ni mo ri ìwa-buburu wọn, li Oluwa wi.
12Nitorina ipa-ọ̀na wọn yio jẹ fun wọn bi ibi yiyọ́ li okunkun: a o tì wọn, nwọn o si ṣubu ninu rẹ̀, nitori emi o mu ibi wá sori wọn, ani ọdun ibẹ̀wo wọn, li Oluwa wi.
13Emi si ti ri were ninu awọn woli Samaria, nwọn sọ asọtẹlẹ li orukọ Baali, nwọn si mu Israeli enia mi ṣina.
14Emi ti ri irira lara awọn woli Jerusalemu, nwọn ṣe panṣaga, nwọn si rìn ninu eke, nwọn mu ọwọ oluṣe-buburu le tobẹ̃, ti kò si ẹnikan ti o yipada kuro ninu ìwa-buburu rẹ̀; gbogbo wọn dabi Sodomu niwaju mi, ati awọn olugbe rẹ̀ bi Gomorra.
15Nitorina bayi li Oluwa awọn ọmọ-ogun wi niti awọn woli; Sa wò o, emi o fi wahala bọ́ wọn, emi o si jẹ ki nwọn ki o mu omi orõro: nitori lati ọdọ awọn woli Jerusalemu ni ibajẹ ti jade lọ si gbogbo ilẹ na.
16Bayi li Oluwa awọn ọmọ-ogun wi: Ẹ máṣe feti si ọ̀rọ awọn woli ti nsọ asọtẹlẹ fun nyin: nwọn sọ nyin di asan, nwọn sọ̀rọ iran inu ara wọn, kì iṣe lati ẹnu Oluwa.
17Nwọn wi sibẹ fun awọn ti o ngàn mi pe, Oluwa ti wi pe, Alafia yio wà fun nyin; nwọn si wi fun olukuluku ti o nrìn nipa agidi ọkàn rẹ̀, pe, kò si ibi kan ti yio wá sori nyin.
18Nitori tali o duro ninu igbimọ Oluwa, ti o woye, ti o si gbọ́ ọ̀rọ rẹ̀? tali o kíyesi ọ̀rọ rẹ̀, ti o si gbà a gbọ́?
19Sa wò o, afẹfẹ-ìji Oluwa! ibinu ti jade! afẹyika ìji yio ṣubu ni ikanra si ori awọn oluṣe buburu:
20Ibinu Oluwa kì yio pada, titi yio fi ṣe e, titi yio si fi mu iro inu rẹ̀ ṣẹ, li ọjọ ikẹhin ẹnyin o mọ̀ ọ daju.
21Emi kò ran awọn woli wọnyi, ṣugbọn nwọn sare: emi kò ba wọn sọ̀rọ, ṣugbọn nwọn sọ asọtẹlẹ.
22Ibaṣepe nwọn duro ni imọran mi, nwọn iba jẹ ki enia mi ki o gbọ́ ọ̀rọ mi, nigbana ni nwọn iba yipada kuro ni ọ̀na buburu wọn, ati kuro ninu buburu iṣe wọn.
23Emi ha iṣe Ọlọrun itosi? li Oluwa wi, kì iṣe Ọlọrun lati okere pẹlu?
24Ẹnikẹni le fi ara rẹ̀ pamọ ni ibi ìkọkọ, ti emi kì yio ri i, li Oluwa wi. Emi kò ha kún ọrun on aiye, li Oluwa wi?
25Emi ti gbọ́ eyiti awọn woli sọ, ti nwọn sọ asọtẹlẹ li orukọ mi wi pe, Mo lá alá! mo lá alá!
26Yio ti pẹ to, ti eyi yio wà li ọkàn awọn woli ti nsọ asọtẹlẹ eke? ani, awọn alasọtẹlẹ ẹ̀tan ọkàn wọn.
27Ti nwọn rò lati mu ki enia mi ki o gbàgbe orukọ mi nipa alá wọn ti nwọn nrọ́, ẹnikini fun ẹnikeji rẹ̀, gẹgẹ bi awọn baba wọn ti gbagbe orukọ mi nitori Baali.
28Woli na ti o lála, jẹ ki o rọ́ ọ; ati ẹniti o ni ọ̀rọ mi, jẹ ki o fi ododo sọ ọ̀rọ mi. Kini iyangbo ni iṣe ninu ọkà, li Oluwa wi?
29Ọ̀rọ mi kò ha dabi iná? li Oluwa wi; ati bi òlu irin ti nfọ́ apata tútu?
30Nitorina sa wò o, emi dojukọ awọn woli, li Oluwa wi, ti o nji ọ̀rọ mi, ẹnikini lati ọwọ ẹnikeji rẹ̀.
31Sa wò o, emi o dojukọ awọn woli, li Oluwa wi, ti nwọn lò ahọn wọn, ti nwọn nsọ jade pe: O wi.
32Sa wò o, emi dojukọ awọn ti o nsọ asọtẹlẹ alá èke, li Oluwa wi, ti nwọn si nrọ́ wọn, ti nwọn si mu enia mi ṣìna nipa eke wọn, ati nipa iran wọn: ṣugbọn emi kò rán wọn, emi kò si paṣẹ fun wọn: nitorina, nwọn kì yio ràn awọn enia yi lọwọ rara, li Oluwa wi.
Ẹrù OLUWA
33Ati nigbati awọn enia yi, tabi woli, tabi alufa, yio bi ọ lere wipe, kini Ọ̀rọ-wuwo Oluwa? nigbana ni iwọ o wi fun wọn Ọ̀rọ-wuwo ni eyi pé: Emi o tì nyin jade, li Oluwa wi.
34Ati woli, ati alufa, ati awọn enia, ti yio wipe, Ọ̀rọ-wuwo Oluwa, emi o jẹ oluwa rẹ̀ ati ile rẹ̀ ni ìya.
35Bayi li ẹnyin o wi, ẹnikini fun ẹnikeji, ati ẹnikan fun arakunrin rẹ̀, pe Kini idahùn Oluwa? ati kini ọ̀rọ Oluwa?
36Ẹ kì o si ranti ọ̀rọ-wuwo Oluwa mọ́, nitori ọ̀rọ olukuluku yio di ẹrù-wuwo fun ontikararẹ̀; nitori ti ẹnyin ti yi ọ̀rọ Ọlọrun alãye dà, Oluwa awọn ọmọ-ogun, Ọlọrun wa.
37Bayi ni iwọ o wi fun woli nì pe: Idahùn wo li Oluwa fi fun ọ? ati pẹlu; Kini Oluwa wi?
38Ṣugbọn bi ẹnyin ba wipe, ọ̀rọ-wuwo Oluwa, nitorina, bayi li Oluwa wi, nitori ẹnyin nsọ ọ̀rọ yi pe, ọ̀rọ-wuwo Oluwa ti emi si ranṣẹ si nyin pe ki ẹ máṣe wipe: ọ̀rọ-wuwọ Oluwa;
39Nitorina, sa wò o, Emi o gbagbe nyin patapata, emi o si kọ̀ nyin silẹ, emi o si tì nyin jade, ati ilu ti mo fi fun nyin ati fun awọn baba nyin, kuro niwaju mi.
40Emi o si mu ẹ̀gan ainipẹkun wá sori nyin, ati itiju lailai, ti a kì yio gbagbe.

Àwon tá yàn lọ́wọ́lọ́wọ́ báyìí:

Jer 23: YBCV

Ìsàmì-sí

Pín

Daako

None

Ṣé o fẹ́ fi àwọn ohun pàtàkì pamọ́ sórí gbogbo àwọn ẹ̀rọ rẹ? Wọlé pẹ̀lú àkántì tuntun tàbí wọlé pẹ̀lú àkántì tí tẹ́lẹ̀