Emi o si kó iyokù agbo-ẹran mi jọ lati inu gbogbo ilẹ, ti mo ti le wọn si, emi o si mu wọn pada wá sinu pápá oko wọn, nwọn o bi si i, nwọn o si rẹ̀ si i.
Emi o gbe oluṣọ-agutan dide fun wọn, ti yio bọ́ wọn: nwọn kì yio bẹ̀ru mọ́, tabi nwọn kì yio si dãmu, bẹ̃li ọkan ninu wọn kì yio si sọnu, li Oluwa wi.