Jer 16

16
Ìfẹ́ OLUWA ní Ìgbésí Ayé Jeremiah
1Ọ̀RỌ Oluwa tọ̀ mi wá wipe:
2Iwọ kò gbọdọ ni aya, bẹ̃ni iwọ kò gbọdọ ni ọmọkunrin tabi ọmọbinrin ni ihinyi.
3Nitori bayi li Oluwa wi niti ọmọkunrin ati ọmọbinrin ti a bi ni ihinyi, ati niti awọn iya wọn ti o bi wọn, ati niti awọn baba wọn ti o bi wọn ni ilẹ yi.
4Nwọn o kú ikú àrun; a kì yio ṣọ̀fọ wọn; bẹ̃ni a kì yio si sin wọn; nwọn o si di àtan lori ilẹ: a o fi idà ati ìyan run wọn, ati okú wọn yio di onjẹ fun ẹiyẹ oju-ọrun, ati fun ẹranko ilẹ.
5Nitori bayi li Oluwa wi, máṣe wọ inu ile ãwẹ̀, bẹ̃ni ki iwọ máṣe lọ sọ̀fọ, tabi lọ pohùnrere ẹkun wọn; nitori emi ti mu alafia mi kuro lọdọ enia yi, li Oluwa wi, ani ãnu ati iyọ́nu.
6Ati ẹni-nla ati ẹni-kekere yio kú ni ilẹ yi, a kì yio sin wọn, bẹ̃ni nwọn kì yio fá ori wọn nitori wọn.
7Bẹ̃ni ẹnikan kì yio bu àkara lati ṣọ̀fọ fun wọn, lati tù wọn ninu nitori okú; bẹ̃ni ẹnikan kì yio fun wọn ni ago itunu mu nitori baba wọn, tabi nitori iya wọn.
8Iwọ kò gbọdọ lọ sinu ile àse, lati joko pẹlu wọn lati jẹ ati lati mu.
9Nitori bayi li Oluwa awọn ọmọ-ogun, Ọlọrun Israeli, wi; Sa wò o, emi o mu ohùn inudidùn, ati ohùn ayọ̀, ohùn ọkọ-iyawo, ati ohùn iyawo dakẹ ni ihinyi loju nyin ati li ọjọ nyin.
10Yio si ṣe, nigbati iwọ o ba fi gbogbo ọ̀rọ wọnyi han enia yi, nwọn o wi fun ọ pe, Ẽṣe ti Oluwa fi sọ̀rọ gbogbo ohun buburu nla yi si wa, tabi kini aiṣedede wa? tabi ẹ̀ṣẹ kini awa da si Oluwa Ọlọrun wa?
11Nigbana ni iwọ o wi fun wọn pe, Nitoripe awọn baba nyin ti kọ̀ mi silẹ, li Oluwa wi, ti nwọn si rìn tọ̀ ọlọrun miran lọ, ti nwọn si sìn wọn, ti nwọn si foribalẹ fun wọn, ti nwọn kọ̀ mi silẹ, ti nwọn kò pa ofin mi mọ;
12Ati pẹlu pe, ẹnyin ti ṣe buburu jù awọn baba nyin lọ: nitorina sa wò o, ẹnyin rìn olukuluku nyin, ni agidi ọkàn buburu rẹ̀, ki ẹnyin ki o má ba gbọ́ temi:
13Emi o si ta nyin nu kuro ni ilẹ yi, sinu ilẹ ti ẹnyin kò mọ̀, ẹnyin tabi awọn baba nyin, nibẹ li ẹnyin o sin ọlọrun miran, lọsan ati loru nibiti emi kì yio ṣe oju-rere fun nyin.
Ìpadàbọ̀ láti Ìgbèkùn
14Nitorina, sa wò o, Bayi li Oluwa wi, ọjọ mbọ̀, ti a kì o wi mọ́ pe, Oluwa mbẹ ti o mu awọn ọmọ Israeli jade kuro ni ilẹ Egipti;
15Ṣugbọn, Oluwa mbẹ ti o mu awọn ọmọ Israeli jade wá kuro ni ilẹ ariwa, ati kuro ni ilẹ nibiti o ti lé wọn si: emi o si tun mu wọn wá si ilẹ wọn, eyiti mo fi fun awọn baba wọn.
Ìjìyà Tí ń Bọ̀
16Sa wò o, emi o ran apẹja pupọ, li Oluwa wi, nwọn o si dẹ wọn: lẹhin eyini, emi o rán ọdẹ pupọ, nwọn o si dẹ wọn lati ori oke-nla gbogbo, ati ori oke kekere gbogbo, ati lati inu palapala okuta jade.
17Nitoriti oju mi mbẹ lara ọ̀na wọn gbogbo: nwọn kò pamọ kuro niwaju mi, bẹ̃ni ẹ̀ṣẹ wọn kò farasin kuro li oju mi.
18Li atetekọṣe, emi o san ẹsan ìwa buburu mejeji wọn, ani, ẹ̀ṣẹ wọn nitoriti nwọn ti bà ilẹ mi jẹ, nwọn ti fi okú ati ohun ẹgbin ati irira wọn kún ilẹ ini mi.
Adura Igbẹkẹ le Jeremiah ninu OLUWA
19Oluwa, agbara mi ati ilu-odi mi! àbo mi li ọjọ ipọnju! awọn orilẹ-ède yio tọ̀ ọ wá, lati ipẹkun aiye, nwọn o si wipe, Lõtọ, awọn baba wa ti jogun eke, ohun asan, iranlọwọ kò si si ninu wọn!
20Enia lè ma dá ọlọrun fun ara rẹ̀: nitori awọn wọnyi kì iṣe ọlọrun?
21Nitorina, sa wò o, emi o mu ki nwọn ki o mọ̀, lẹ̃kan yi, emi o si mu ki nwọn ki o mọ̀ ọwọ mi ati ipa mi; nwọn o si mọ̀ pe, orukọ mi ni JEHOFA.

Àwon tá yàn lọ́wọ́lọ́wọ́ báyìí:

Jer 16: YBCV

Ìsàmì-sí

Pín

Daako

None

Ṣé o fẹ́ fi àwọn ohun pàtàkì pamọ́ sórí gbogbo àwọn ẹ̀rọ rẹ? Wọlé pẹ̀lú àkántì tuntun tàbí wọlé pẹ̀lú àkántì tí tẹ́lẹ̀