A. Oni 16
16
Samsoni ní Ìlú Gasa
1SAMSONI si lọ si Gasa, o si ri obinrin panṣaga kan nibẹ̀, o si wọle tọ̀ ọ.
2Awọn ara Gasa si gbọ́ pe, Samsoni wá si ihin. Nwọn si yi i ká, nwọn lùmọ́ ni gbogbo oru na li ẹnu-bode ilu na, nwọn si dakẹ jẹ ni gbogbo oru na, wipe, Li owurọ̀ nigbati ilẹ ba mọ́, li awa a pa a.
3Samsoni si dubulẹ titi o fi di ãrin ọganjọ, o si dide lãrin ọganjọ, o si gbé ilẹkun-ibode ilu na, ati opó mejeji, o si fà wọn tu pẹlu idabu-ilẹ̀kùn, o gbé wọn lé ejika rẹ̀, o si rù wọn lọ si ori òke kan ti o wà niwaju Hebroni.
Samsoni ati Delila
4O si ṣe lẹhin eyinì, o si fẹ́ obinrin kan li afonifoji Soreki, a si ma pè orukọ rẹ̀ ni Delila.
5Awọn ijoye Filistini tọ̀ ọ wá, nwọn si wi fun u pe, Tàn a, ki o si mọ̀ ibiti agbara nla rẹ̀ gbé wà, ati bi awa o ti ṣe le bori rẹ̀, ki awa ki o le dè e lati jẹ ẹ niyà: olukuluku wa yio si fun ọ ni ẹdẹgbẹfa owo fadakà.
6Delila si wi fun Samsoni pe, Emi bẹ̀ ọ, wi fun mi, nibo li agbara nla rẹ gbé wà, ati kili a le fi dè ọ lati jẹ ọ niyà.
7Samsoni si wi fun u pe, Bi a ba fi okùn tutù meje ti a kò ságbẹ dè mi, nigbana li emi o di alailera, emi o si dabi ọkunrin miran.
8Nigbana li awọn ijoye Filistini mú okùn tutù meje tọ̀ ọ wá ti a kò ságbẹ, o si fi okùn wọnni dè e.
9Obinrin na si ní awọn kan, ti nwọn lumọ́ ninu yará. On si wi fun u pe, Awọn Filistini dé, Samsoni. On si já okùn na, gẹgẹ bi owú ti ijá nigbati o ba kan iná. Bẹ̃li a kò mọ̀ agbara rẹ̀.
10Delila si wi fun Samsoni pe, Kiyesi i, iwọ tàn mi jẹ, o si purọ́ fun mi: wi fun mi, emi bẹ̀ ọ, kili a le fi dè ọ.
11On si wi fun u pe, Bi nwọn ba le fi okùn titun ti a kò ti lò rí dè mi le koko, nigbana li emi o di alailera, emi o si dabi ọkunrin miran.
12Bẹ̃ni Delila mú okùn titun, o si fi dè e, o si wi fun u pe, Awọn Filistini dé, Samsoni. Awọn ti o lumọ́ dè e wà ninu yará. On si já wọn kuro li apa rẹ̀ bi owu.
13Delila si wi fun Samsoni pe, Titi di isisiyi iwọ ntàn mi ni, iwọ si npurọ́ fun mi: sọ fun mi, kili a le fi dè ọ. On si wi fun u pe, Bi iwọ ba wun ìdi irun meje ti o wà li ori mi.
14On si fi ẽkàn dè e, o si wi fun u pe, Awọn Filistini dé, Samsoni. O si jí kuro li oju orun rẹ̀, o si fà ẽkàn ìti na pẹlu ihunṣọ rẹ̀ lọ.
15On si wi fun u pe, Iwọ ha ti ṣe wipe, Emi fẹ́ ọ, nigbati ọkàn rẹ kò ṣedede pẹlu mi? iwọ ti tàn mi ni ìgba mẹta yi, iwọ kò si sọ ibiti agbara nla rẹ gbé wà fun mi.
16O si ṣe, nigbati o fi ọ̀rọ rẹ̀ rọ̀ ọ li ojojumọ́, ti o si ṣe e laisimi, tobẹ̃ ti sũru fi tan ọkàn rẹ̀ dé ikú.
17Li on si sọ gbogbo eyiti o wà li ọkàn rẹ̀ fun u, o si wi fun u pe, Abẹ kò kàn ori mi rí; nitoripe Nasiri Ọlọrun li emi iṣe lati inu iya mi wá: bi a ba fá ori mi, nigbana li agbara mi yio lọ kuro lọdọ mi, emi o si di alailera, emi o si dabi ọkunrin miran.
18Nigbati Delila ri pe, o sọ gbogbo ọkàn rẹ̀ fun u, o si ranṣẹ pè awọn ijoye Filistini, wipe, Ẹ gòke wá lẹ̃kan yi, nitoriti o sọ gbogbo ọkàn rẹ̀ fun mi. Nigbana li awọn ijoye Filistini wá sọdọ rẹ̀, nwọn si mú owo li ọwọ́ wọn.
19O si mú ki o sùn li ẽkun rẹ̀; o si pè ọkunrin kan, o si mu ki o fá ìdi irun mejeje ori rẹ̀; on si bẹ̀rẹsi pọ́n ọ loju, agbara rẹ̀ si ti lọ kuro lọdọ rẹ̀.
20On si wipe, Awọn Filistini dé, Samsoni. O si jí kuro li oju õrun rẹ̀, o si wipe, Emi o jade lọ bi ìgba iṣaju, ki emi ki o si gbọ̀n ara mi. On kò si mọ̀ pe OLUWA ti kuro lọdọ on.
21Awọn Filistini sì mú u, nwọn si yọ ọ li oju mejeji; nwọn si mú u sọkalẹ wá si Gasa, nwọn si fi ṣẹkẹṣẹkẹ̀ idẹ dè e: on si nlọ-ọlọ ni ile-tubu.
22Ṣugbọn irun ori rẹ̀ bẹ̀rẹsi hù lẹhin igbati a ti fá a tán.
Ikú Samsoni
23Nigbana ni awọn ijoye Filistini kó ara wọn jọ lati ru ẹbọ nla kan si Dagoni oriṣa wọn, ati lati yọ̀: nitoriti nwọn wipe, Oriṣa wa fi Samsoni ọtá wa lé wa lọwọ.
24Nigbati awọn enia si ri i, nwọn fi iyin fun oriṣa wọn: nitoriti nwọn wipe, Oriṣa wa fi ọtá wa lé wa lọwọ, ẹniti npa ilẹ wa run, ti o si pa ọ̀pọlọpọ enia ninu wa.
25O si ṣe, nigbati inu wọn dùn, ni nwọn wipe, Ẹ pè Samsoni, ki o wa ṣiré fun wa. Nwọn si pè Samsoni lati inu ile-itubu wá; o si ṣiré niwaju wọn: nwọn si mu u duro lãrin ọwọ̀n meji.
26Samsoni si wi fun ọmọkunrin ti o di ọwọ́ rẹ̀ mú pe, Jẹ ki emi ki o fọwọbà awọn ọwọ̀n ti ile joko lé, ki emi ki o le faratì wọn.
27Njẹ ile na kún fun ọkunrin ati obinrin; gbogbo awọn ijoye Filistini si wà nibẹ̀; awọn ti o si wà lori orule, ati ọkunrin ati obinrin, o to ìwọn ẹgbẹdogun enia, ti nworan Samsoni nigbati o nṣiré.
28Samsoni si kepè OLUWA, o si wipe, Oluwa ỌLỌRUN, emi bẹ̀ ọ, ranti mi, ki o si jọ̃ fun mi li agbara lẹ̃kanṣoṣo yi, Ọlọrun, ki emi ki o le gbẹsan lẹ̃kan lara awọn Filistini nitori oju mi mejeji.
29Samsoni si dì ọwọ̀n ãrin mejeji na mú lori eyiti ile na joko, o si faratì wọn, o fi ọwọ́ ọtún rẹ̀ mú kan, o si fi ọwọ́ òsi rẹ̀ mú ekeji.
30Samsoni si wipe, Jẹ ki nkú pẹlu awọn Filistini. O si fi gbogbo agbara rẹ̀ bẹ̀rẹ; ile na si wó lù awọn ijoye wọnni, ati gbogbo enia ti o wà ninu rẹ̀. Bẹ̃li awọn okú ti o pa ni ikú rẹ̀, pọjù awọn ti o pa li ãyè rẹ̀ lọ.
31Nigbana li awọn arakunrin rẹ̀ ati gbogbo idile baba rẹ̀ sọkalẹ wá, nwọn si gbé e gòke, nwọn si sin i lãrin Sora on Eṣtaolu ni ibojì Manoa baba rẹ̀. O si ṣe idajọ Israeli li ogún ọdún.
Àwon tá yàn lọ́wọ́lọ́wọ́ báyìí:
A. Oni 16: YBCV
Ìsàmì-sí
Pín
Daako
Ṣé o fẹ́ fi àwọn ohun pàtàkì pamọ́ sórí gbogbo àwọn ẹ̀rọ rẹ? Wọlé pẹ̀lú àkántì tuntun tàbí wọlé pẹ̀lú àkántì tí tẹ́lẹ̀
Yoruba Bible Crowther Version © The Bible Society of Nigeria, 2012.