Jak Ọ̀rọ̀ Iṣaaju

Ọ̀rọ̀ Iṣaaju
Ìwé láti Ọ̀dọ̀ Jakọbu jẹ́ àkójọ oríṣìíríṣìí ìlànà ati ẹ̀kọ́ tí a kọ “sí gbogbo eniyan Ọlọrun tí ó fọ́n káàkiri gbogbo ayé.” Oríṣìíríṣìí ọ̀rọ̀ àpèjúwe tí ó múni lọ́kàn ni ẹni tí ó kọ ìwé yìí lò láti gbé ìlànà rẹ̀ kalẹ̀ nípa ọgbọ́n tí ó ṣeé múlò ati ìtọ́ni fún ìhùwàsí ati ìṣe onigbagbọ. Ọpọlọpọ kókó ọ̀rọ̀ ni ó mẹ́nu bà, ó sì sọ ìhà tí onigbagbọ níláti kọ sí àwọn nǹǹkan bí ọrọ̀, àìní, ìdánwò, ìwà rere, igbagbọ ati iṣẹ́, fífi èdè àjèjì sọ̀rọ̀, ọgbọ́n, ìjà, ìgbéraga ati ìrẹ̀lẹ̀; dídá àwọn ẹlòmííràn lẹ́jọ́, ẹnu fífọ́n, sùúrù ati adura.
Ìwé yìí tẹnu mọ́ ọn pé ó ṣe pataki pé kí iṣẹ́ kún igbagbọ ninu mímú ẹ̀sìn igbagbọ lò.
Àwọn Ohun tí ó wà ninu Ìwé yìí ní Ìsọ̀rí-ìsọ̀rí
Ọ̀rọ̀ Iṣaaju 1:1
Igbagbọ ati ọgbọ́n 1:2-8
Àìní ati ọrọ̀ 1:9-11
Ìdẹwò ati ìdánwò 1:12-18
Gbígbọ́ ati ṣíṣe 1:19-27
Ìkìlọ̀ nípa yíya àwọn kan sọ́tọ̀ 2:1-13
Igbagbọ ati iṣẹ́ 2:14-26
Onigbagbọ ati ahọ́n rẹ̀ 3:1-18
Onigbagbọ ati ayé 4:1—5:6
Oríṣìíríṣìí ìlànà 5:7-20

Àwon tá yàn lọ́wọ́lọ́wọ́ báyìí:

Jak Ọ̀rọ̀ Iṣaaju: YBCV

Ìsàmì-sí

Pín

Daako

None

Ṣé o fẹ́ fi àwọn ohun pàtàkì pamọ́ sórí gbogbo àwọn ẹ̀rọ rẹ? Wọlé pẹ̀lú àkántì tuntun tàbí wọlé pẹ̀lú àkántì tí tẹ́lẹ̀

YouVersion nlo awọn kuki lati ṣe adani iriri rẹ. Nipa lilo oju opo wẹẹbu wa, o gba lilo awọn kuki wa gẹgẹbi a ti ṣalaye ninu Eto Afihan wa