Jak 4

4
Bíbá Ayé Rẹ́
1NIBO ni ogun ti wá, nibo ni ija si ti wá larin nyin? lati inu eyi ha kọ? lati inu ifẹkufẹ ara nyin, ti njagun ninu awọn ẹ̀ya-ara nyin?
2Ẹnyin nfẹ, ẹ kò si ni: ẹnyin npa, ẹ si nṣe ilara, ẹ kò si le ni: ẹnyin njà, ẹnyin si njagun; ẹ ko ni, nitoriti ẹnyin kò bère.
3Ẹnyin bère, ẹ kò si ri gbà, nitoriti ẹnyin ṣì i bère, ki ẹnyin ki o le lò o fun ifẹkufẹ ara nyin.
4Ẹnyin panṣaga ọkunrin, ati panṣaga obinrin, ẹ kò mọ̀ pe ìbarẹ́ aiye ìṣọtá Ọlọrun ni? nitorina ẹnikẹni ti o ba fẹ lati jẹ́ ọrẹ aiye di ọtá Ọlọrun.
5Ẹnyin ṣebi iwe-mimọ́ sọ lasan pe, Ẹmí ti o fi sinu wa njowu gidigidi lori wa?
6Ṣugbọn o nfunni li ore-ọfẹ si i. Nitorina li o ṣe wipe, Ọlọrun kọ oju ija si awọn agberaga, ṣugbọn o fi ore-ọfẹ fun awọn onirẹlẹ ọkàn.
7Nitorina ẹ tẹriba fun Ọlọrun. Ẹ kọ oju ija si Èṣu, on ó si sá kuro lọdọ nyin.
8Ẹ sunmọ Ọlọrun, on o si sunmọ nyin, Ẹ wẹ̀ ọwọ́ nyin mọ́, ẹnyin ẹlẹṣẹ; ẹ si ṣe ọkàn nyin ni mimọ́, ẹnyin oniye meji.
9Ki inu nyin ki o bajẹ, ki ẹ si gbàwẹ, ki ẹ si mã sọkun: ẹ jẹ ki ẹrín nyin ki o di àwẹ, ati ayọ̀ nyin ki o di ikãnu.
10Ẹ rẹ̀ ara nyin silẹ niwaju Oluwa, on o si gbé nyin ga.
Dídá Arakunrin Wa Lẹ́jọ́
11Ará, ẹ máṣe sọ̀rọ ibi si ara nyin. Ẹniti o ba nsọ̀rọ ibi si arakunrin rẹ̀, ti o si ndá arakunrin rẹ̀ lẹjọ, o nsọ̀rọ ibi si ofin, o si ndá ofin lẹjọ; ṣugbọn bi iwọ ba ndá ofin lẹjọ, iwọ kì iṣe oluṣe ofin, bikoṣe onidajọ.
12Olofin ati onidajọ kanṣoṣo ni mbẹ, ani ẹniti ó le gbala ti o si le parun; ṣugbọn tani iwọ ti ndá ẹnikeji rẹ lẹjọ?
Ìkìlọ̀ nípa Fífọ́nnu
13Ẹ wá nisisiyi, ẹnyin tí nwipe, Loni tabi lọla awa ó lọ si ilu bayi, a o si ṣe ọdún kan nibẹ, a o si ṣòwo, a o si jère:
14Nigbati ẹnyin kò mọ̀ ohun ti yio hù lọla. Kili ẹmí nyin? Ikũku sá ni nyin, ti o hàn nigba diẹ, lẹhinna a si túka lọ.
15Eyi ti ẹ bá fi wipe, bi Oluwa ba fẹ, awa o wà lãye, a o si ṣe eyi tabi eyini.
16Ṣugbọn nisisiyi ẹnyin nṣeféfe ninu ifọnnu nyin: gbogbo irú iṣeféfe bẹ̃, ibi ni.
17Nitorina ẹniti o ba mọ̀ rere iṣe ti kò si ṣe, ẹ̀ṣẹ ni fun u.

Àwon tá yàn lọ́wọ́lọ́wọ́ báyìí:

Jak 4: YBCV

Ìsàmì-sí

Pín

Daako

None

Ṣé o fẹ́ fi àwọn ohun pàtàkì pamọ́ sórí gbogbo àwọn ẹ̀rọ rẹ? Wọlé pẹ̀lú àkántì tuntun tàbí wọlé pẹ̀lú àkántì tí tẹ́lẹ̀