Isa 65:20-25

Isa 65:20-25 YBCV

Ki yio si ọmọ-ọwọ nibẹ ti ọjọ rẹ̀ kì yio pẹ́, tabi àgba kan ti ọjọ rẹ̀ kò kún: nitori ọmọde yio kú li ọgọrun ọdun; ṣugbọn ẹlẹṣẹ ọlọgọrun ọdun yio di ẹni-ifibu. Nwọn o si kọ ile, nwọn o si gbe inu wọn; nwọn o si gbìn ọgba àjara, nwọn o si jẹ eso wọn. Nwọn kì yio kọ ile fun ẹlomiran lati gbé, nwọn kì yio gbìn fun ẹlomiran lati jẹ: nitori gẹgẹ bi ọjọ igi li ọjọ awọn enia mi ri, awọn ayanfẹ mi yio si jìfà iṣẹ ọwọ́ wọn. Nwọn kì yio ṣiṣẹ lasan, nwọn kì yio bimọ fun wahala: nitori awọn ni iru alabukun Oluwa ati iru-ọmọ wọn pẹlu wọn. Yio si ṣe, pe, ki nwọn ki o to pè, emi o dahùn; ati bi nwọn ba ti nsọ̀rọ lọwọ, emi o gbọ́. Ikõko ati ọdọ-agutan yio jumọ jẹ pọ̀, kiniun yio si jẹ koriko bi akọ-mãlu: erupẹ ni yio jẹ onjẹ ejò. Nwọn kì yio panilara, tabi ki nwọn panirun ni gbogbo oke mimọ́ mi, li Oluwa wi.