Isa 64:1-12

Isa 64:1-12 YBCV

IWỌ iba jẹ fà awọn ọrun ya, ki iwọ si sọkalẹ, ki awọn oke-nla ki o le yọ́ niwaju rẹ. Gẹgẹ bi igbati iná ileru ti njo, bi iná ti imu omi hó, lati sọ orukọ rẹ di mimọ̀ fun awọn ọta rẹ, ki awọn orilẹ-ède ki o le warìri niwaju rẹ! Nigbati iwọ ṣe nkan wọnni ti o lẹ̀ru ti awa kò fi oju sọna fun, iwọ sọkalẹ wá, awọn oke-nla yọ́ niwaju rẹ. Nitori lati ipilẹṣẹ aiye wá, a kò ti igbọ́, bẹ̃ni eti kò ti gbọ́ ọ, bẹ̃ni oju kò ti iri Ọlọrun kan lẹhin rẹ, ti o ti pèse fun ẹniti o duro dè e. Iwọ pade ẹniti nyọ̀ ti o nṣiṣẹ ododo, ti o ranti rẹ li ọ̀na rẹ: kiyesi i, iwọ binu; nitori awa ti dẹṣẹ̀; a si pẹ ninu wọn, a o ha si là? Gbogbo wa si dabi ohun aimọ́, gbogbo ododo wa si dabi akisa ẹlẹgbin; gbogbo wa si rẹ̀ bi ewe; aiṣedede wa si mu wa kuro bi afẹfẹ. Kò si ẹniti npè orukọ rẹ, ti o si rú ara rẹ̀ soke lati di ọ mu: nitori iwọ ti pa oju rẹ mọ kuro lara wa, iwọ si ti run wa, nitori aiṣedede wa. Ṣugbọn nisisiyi, Oluwa, iwọ ni baba wa; awa ni amọ̀, iwọ si ni ọ̀mọ; gbogbo wa si ni iṣẹ ọwọ́ rẹ. Máṣe binu kọja àla, Oluwa, ki o má si ranti aiṣedede wa titilai: kiyesi i, wò, awa bẹ̀ ọ, enia rẹ ni gbogbo wa iṣe. Awọn ilu mimọ́ rẹ di aginju, Sioni dí aginju, Jerusalemu di ahoro. Ile wa mimọ́ ati ologo, nibiti awọn baba wa ti nyìn ọ, li a fi iná kun: gbogbo ohun ãyo wa si ti run. Iwọ o ha da ara rẹ duro nitori nkan wọnyi, Oluwa? iwọ o ha dakẹ, ki o si pọn wa loju kọja àla?