Ati awọn ọmọ alejò ti nwọn dà ara pọ̀ mọ Oluwa, lati sìn i, ati lati fẹ orukọ Oluwa, lati jẹ iranṣẹ rẹ̀, olukuluku ẹniti o pa ọjọ isimi mọ laisọ ọ di aimọ́, ti o si di majẹmu mi mu; Awọn li emi o si mu wá si oke-nla mimọ́ mi, emi o si mu inu wọn dùn, ninu ile adua mi: ẹbọ sisun wọn, ati irubọ wọn, yio jẹ itẹwọgba lori pẹpẹ mi; nitori ile adua li a o ma pe ile mi fun gbogbo enia. Oluwa Jehofah, ẹniti o ṣà àtanu Israeli jọ wipe, Emi o ṣà awọn ẹlomiran jọ sọdọ rẹ̀, pẹlu awọn ti a ti ṣà jọ sọdọ rẹ̀.
Kà Isa 56
Feti si Isa 56
Pín
Fi gbogbo Èyá wéra: Isa 56:6-8
Ṣe àfipamọ́ àwọn ẹsẹ, kàá ní aìsìní orí ayélujára, wo àwọn àgékúrú ìkọ́ni, àti díẹ̀ síi!
Ilé
Bíbélì
Àwon ètò
Àwon Fídíò