GBỌ ti emi, ẹnyin ti ntẹle ododo, ẹnyin ti nwá Oluwa; wò apáta nì ninu eyiti a ti gbẹ́ nyin, ati ihò kòto nì nibiti a gbe ti wà nyin.
Ẹ wò Abrahamu baba nyin, ati Sara ti o bi nyin; nitori on nikan ni mo pè, mo si sure fun u, mo si mu u pọ̀ si i.
Nitori Oluwa yio tù Sioni ninu; yio tú gbogbo ibi ofo rẹ̀ ninu; yio si ṣe aginju rẹ̀ bi Edeni, ati aṣálẹ rẹ̀ bi ọgbà Oluwa, ayọ̀ ati inudidùn li a o ri ninu rẹ̀, idupẹ, ati ohùn orin.
Tẹtilelẹ si mi, ẹnyin enia mi; si fi eti si mi, iwọ orilẹ-ède mi: nitori ofin kan yio ti ọdọ mi jade lọ, emi o si gbe idajọ mi kalẹ fun imọlẹ awọn enia.
Ododo mi wà nitosí; igbala mi ti jade lọ, apá mi yio si ṣe idajọ awọn enia; awọn erekùṣu yio duro dè mi, apá mi ni nwọn o si gbẹkẹle.
Ẹ gbé ojú nyin soke si awọn ọrun, ki ẹ si wò aiye nisalẹ: nitori awọn ọrun yio fẹ́ lọ bi ẹ̃fin, aiye o si di ogbó bi ẹwù, awọn ti ngbe inu rẹ̀ yio si kú bakanna: ṣugbọn igbala mi o wà titi lai, ododo mi kì yio si parẹ́.
Gbọ́ ti emi, ẹnyin ti o mọ̀ ododo, enia ninu aiya ẹniti ofin mi mbẹ; ẹ máṣe bẹ̀ru ẹgàn awọn enia, ẹ má si ṣe foyà ẹsín wọn.
Nitori kòkoro yio jẹ wọn bi ẹ̀wu, idin yio si jẹ wọn bi irun agutan: ṣugbọn ododo mi yio wà titi lai, ati igbala mi lati iran de iran.
Ji, ji, gbe agbara wọ̀, Iwọ apa Oluwa; ji, bi li ọjọ igbãni, ni iran atijọ. Iwọ kọ́ ha ke Rahabu, ti o si ṣá Dragoni li ọgbẹ́?
Iwọ kọ́ ha gbẹ okun, omi ibu nla wọnni? ti o ti sọ ibú okun di ọ̀na fun awọn ẹni ìrapada lati gbà kọja?
Nitorina awọn ẹni-ìrapada Oluwa yio pada, nwọn o si wá si Sioni ti awọn ti orin; ayọ̀ ainipẹkun yio si wà li ori wọn: nwọn o ri inudidùn ati ayọ̀ gbà; ikãnu ati ọ̀fọ yio fò lọ.