Isa 49:8-16

Isa 49:8-16 YBCV

Bayi ni Oluwa wi, Li akoko itẹwọgba emi ti gbọ́ tirẹ, ati li ọjọ igbala, mo si ti ràn ọ lọwọ: emi o si pa ọ mọ, emi o si fi ọ ṣe majẹmu awọn enia, lati fi idi aiye mulẹ, lati mu ni jogun ahoro ilẹ nini wọnni. Ki iwọ ki o le wi fun awọn igbekùn pe, Ẹ jade lọ; fun awọn ti o wà ni okùnkun pe, Ẹ fi ara nyin hàn. Nwọn o jẹ̀ li ọ̀na wọnni, pápa ijẹ wọn o si wà ni gbogbo ibi giga. Ebi kì yio pa wọn, bẹ̃ni ongbẹ kì yio si gbẹ wọn; õru kì yio mu wọn, bẹ̃ni õrùn kì yio si pa wọn: nitori ẹniti o ti ṣãnu fun wọn yio tọ́ wọn, ani nihà isun omi ni yio dà wọn. Emi o si sọ gbogbo awọn òke-nla mi wọnni di ọ̀na, a o si gbe ọ̀na opopo mi wọnni ga. Kiye si i, awọn wọnyi yio wá lati ọ̀na jijìn: si wò o, awọn wọnyi lati ariwa wá; ati lati iwọ-õrun wá, ati awọn wọnyi lati ilẹ Sinimu wá. Kọrin, ẹnyin ọrun; ki o si yọ̀, iwọ aiye; bú jade ninu orin, ẹnyin oke-nla: nitori Oluwa ti tù awọn enia rẹ̀ ninu, yio si ṣãnu fun awọn olupọnju rẹ̀. Ṣugbọn Sioni wipe, Oluwa ti kọ̀ mi silẹ; Oluwa mi si ti gbagbe mi. Obinrin ha lè gbagbe ọmọ ọmú rẹ̀ bi, ti kì yio fi ṣe iyọ́nu si ọmọ inu rẹ̀? lõtọ, nwọn le gbagbe, ṣugbọn emi kì yio gbagbe rẹ. Kiye si i, emi ti kọ ọ si atẹlẹwọ mi: awọn odi rẹ mbẹ niwaju mi nigbagbogbo.