Isa 49:8-16

Isa 49:8-16 Yoruba Bible (YCE)

OLUWA ní, “Ní àkókò ìtẹ́wọ́gbà mo dá ọ lóhùn, lọ́jọ́ ìgbàlà, mo ràn ọ́ lọ́wọ́. Mo ti pa ọ́ mọ́, mo sì ti fi ọ́ dá majẹmu pẹlu àwọn aráyé, láti fìdí ilẹ̀ náà múlẹ̀, láti pín ilẹ̀ tí ó ti di ahoro. Kí o máa sọ fún àwọn ẹlẹ́wọ̀n pé, ‘Ẹ jáde,’ ati fún àwọn tí ó wà ninu òkùnkùn pé, ‘Ẹ farahàn.’ Wọn óo rí ohun jíjẹ ní gbogbo ọ̀nà, gbogbo orí òkè yóo sì jẹ́ ibùjẹ fún wọn. Ebi kò ní pa wọ́n, òùngbẹ kò sì ní gbẹ wọ́n, atẹ́gùn gbígbóná kò ní fẹ́ lù wọ́n, bẹ́ẹ̀ ni oòrùn kò ní pa wọ́n, nítorí ẹni tí ó ṣàánú wọn ni yóo máa darí wọn, yóo sì mú wọn gba ẹ̀gbẹ́ omi tí ń ṣàn. “N óo sọ gbogbo òkè mi di ojú ọ̀nà, n óo kún gbogbo òpópó ọ̀nà mi. Wò ó! Òkèèrè ni èyí yóo ti wá, láti àríwá ati láti ìwọ̀ oòrùn, àní láti ilẹ̀ Sinimu.” Kí ọ̀run kọrin ayọ̀, kí ayé kún fún ayọ̀, ẹ̀yin òkè, ẹ máa kọrin, nítorí, OLUWA ti tu àwọn eniyan rẹ̀ ninu, yóo ṣàánú àwọn eniyan rẹ̀ tí ìyà ń jẹ. Sioni ń wí pé, “OLUWA ti kọ̀ mí sílẹ̀, Oluwa mi ti gbàgbé mi.” OLUWA dáhùn pé, “Ǹjẹ́ abiyamọ le gbàgbé ọmọ tí ń fún lọ́mú? Ṣé ó le má ṣàánú ọmọ bíbí inú rẹ̀? Bí àwọn wọnyi tilẹ̀ gbàgbé. Èmi kò ní gbàgbé rẹ. Wò ó! Mo ti fi gègé fín orúkọ rẹ sí àtẹ́lẹwọ́ mi, àwọn odi rẹ sì ńbẹ níwájú mi nígbà gbogbo.

Isa 49:8-16 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní (YCB)

Ohun tí OLúWA wí nìyìí: “Ní àkókò ojúrere mi, èmi yóò dá ọ lóhùn, àti ní ọjọ́ ìgbàlà, èmi yóò ràn ọ́ lọ́wọ́; Èmi yóò pa ọ́ mọ́, n ó sì ṣe ọ́ láti jẹ́ májẹ̀mú fún àwọn ènìyàn, láti mú ilẹ̀ padà bọ̀ sípò àti láti ṣe àtúnpín ogún rẹ̀ tí ó ti dahoro, Láti sọ fún àwọn ìgbèkùn pé, ‘Ẹ jáde wá’ àti fún àwọn tí ó wà nínú òkùnkùn pé, ‘Ẹ gba òmìnira!’ “Wọn yóò máa jẹ ní ẹ̀bá ọ̀nà àti koríko tútù lórí òkè aláìléwéko. Ebi kì yóò pa wọ́n bẹ́ẹ̀ ni òǹgbẹ kì yóò gbẹ wọ́n, tàbí kí ooru inú aṣálẹ̀ tàbí oòrùn kí ó pa wọ́n. Ẹni tí ó ṣàánú fún wọn ni yóò máa tọ́ wọn, tí yóò sì mú wọn lọ sí ibi orísun omi. Èmi yóò sọ gbogbo àwọn òkè-ńlá mi di ojú ọ̀nà àti gbogbo òpópónà mi ni a ó gbé sókè. Kíyèsi i, wọn yóò wá láti ọ̀nà jíjìn àwọn díẹ̀ láti àríwá àti àwọn díẹ̀ láti ìwọ̀-oòrùn, àwọn díẹ̀ láti ẹkùn Siene.” Ẹ hó fún ayọ̀, ẹyin ọ̀run; yọ̀, ìwọ ilẹ̀ ayé; bú sórin, ẹ̀yin òkè ńlá! Nítorí OLúWA tu àwọn ènìyàn rẹ̀ nínú yóò sì ṣàánú fún àwọn ẹni tí a ń pọ́n lójú. Ṣùgbọ́n Sioni sọ pé, “OLúWA ti kọ̀ mí sílẹ̀, Olúwa ti gbàgbé è mi.” “Ǹjẹ́ abiyamọ ha le gbàgbé ọmọ ọmú rẹ̀ kí ó má sì ṣàánú fún ọmọ rẹ̀ tí ó ti bí? Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé òun le gbàgbé Èmi kì yóò gbàgbé rẹ! Kíyèsi i, mo ti kọ ọ́ sí àtẹ́lẹwọ́ mi ògiri rẹ wà níwájú mi nígbà gbogbo.