ṢUGBỌN nisisiyi, gbọ́, iwọ Jakobu iranṣẹ mi, ati Israeli ẹniti mo ti yàn: Bayi ni Oluwa wi, ẹniti o dá ọ, ti o mọ ọ lati inu wá, ti yio si ràn ọ lọwọ; Má bẹ̀ru, iwọ Jakobu, iranṣẹ mi; ati iwọ Jeṣuruni ti mo ti yàn. Nitori emi o dà omi lu ẹniti ongbẹ ngbẹ, ati iṣàn-omi si ilẹ gbigbẹ: emi o dà ẹmi mi si iru rẹ, ati ibukun mi si iru-ọmọ rẹ. Nwọn o si hù soke lãrin koriko, bi igi willo leti ipadò. Ọkan yio wipe, ti Oluwa li emi, omiran yio si pe ara rẹ̀ nipa orukọ Jakobu; omiran yio si fi ọwọ́ rẹ̀ kọ pe, on ni ti Oluwa, yio si pe apele rẹ̀ nipa orukọ Israeli.
Kà Isa 44
Feti si Isa 44
Pín
Fi gbogbo Èyá wéra: Isa 44:1-5
Ṣe àfipamọ́ àwọn ẹsẹ, kàá ní aìsìní orí ayélujára, wo àwọn àgékúrú ìkọ́ni, àti díẹ̀ síi!
Ilé
Bíbélì
Àwon ètò
Àwon Fídíò