Isa 38

38
Àìsàn Hesekaya ati Ìmúláradá Rẹ̀
1LI ọjọ wọnni Hesekiah ṣaisàn de oju ikú. Woli Isaiah ọmọ Amosi si wá sọdọ rẹ̀, o si wi fun u pe, Bayi ni Oluwa wi, Palẹ ile rẹ mọ́: nitori iwọ o kú, o ki yio si yè.
2Nigbana ni Hesekiah yi oju rẹ̀ si ogiri, o si gbadura si Oluwa.
3O si wipe, Nisisiyi, Oluwa, mo bẹ̀ ọ, ranti bi mo ti rìn niwaju rẹ li otitọ ati pẹlu aiya pipé, ati bi mo si ti ṣe eyiti o dara li oju rẹ. Hesekiah si sọkún pẹrẹ̀pẹrẹ̀.
4Ọ̀rọ Oluwa si tọ̀ Isaiah wá, wipe,
5Lọ, si wi fun Hesekiah pe, Bayi ni Oluwa, Ọlọrun Dafidi baba rẹ wi, mo ti gbọ́ adura rẹ, mo ti ri omije rẹ: kiyesi i emi o fi ọdun mẹ̃dogun kún ọjọ rẹ.
6Emi o si gbà ọ ati ilu yi lọwọ ọba Assiria: emi o si dãbò bò ilu yi.
7Eyi yio sì jẹ àmi fun ọ lati ọdọ Oluwa wá, pe, Oluwa yio ṣe nkan yi ti o ti sọ;
8Kiyesi i, emi o tún mu ìwọn òjiji ti o ti sọkalẹ lara agogo-õrùn Ahasi pada ni ìwọn mẹwa. Bẹ̃ni õrun pada ni ìwọn mẹwa ninu ìwọn ti o ti sọkalẹ.
Orin Ọpẹ́ tí Hesekaya kọ
9Iwe Hesekiah ọba Juda, nigbati o fi ṣaisàn, ti o si sàn ninu aisàn rẹ̀:
10Mo ni, ni ìke-kuro ọjọ mi, emi o lọ si ẹnu-ọnà isà-okú; a dù mi ni iyokù ọdun mi.
11Mo ni, emi kì yio ri Oluwa, ani Oluwa, ni ilẹ alãyè: emi kì yio ri enia mọ lãrin awọn ti ngbé ibi idakẹ.
12Ọjọ ori mi lọ, a si ṣi i kuro lọdọ mi bi àgọ olùṣọ agutan: mo ti ké ẹmi mi kuro bi ahunṣọ: yio ké mi kuro bi fọ́nran-òwu tinrin: lati ọ̀san de oru ni iwọ o mu mi de òpin mi.
13Mo ṣirò titi di òwurọ, pe, bi kiniun, bẹ̃ni yio fọ́ gbogbo egungun mi; lati ọ̀san de oru ni iwọ o mu mi de òpin mi.
14Bi akọ̀ tabi alapandẹ̀dẹ, bẹ̃ni mo dún; mo kãnu bi oriri: ãrẹ̀ mu oju mi fun iwòke: Oluwa, ara nni mi: ṣe onigbọwọ mi.
15Kili emi o wi? o ti sọ fun mi, on tikalarẹ̀ si ti ṣe e: emi o ma lọ jẹjẹ fun gbogbo ọdun mi ni kikorò ọkàn mi.
16Oluwa, nipa nkan wọnyi li enia ima wà, ati ni gbogbo nkan wọnyi ni iye ẹmi mi: bẹ̃ni iwọ o mu mi lara dá, iwọ o si mu mi yè.
17Kiyesi i, mo ti ni ikorò nla nipò alafia: ṣugbọn iwọ ti fẹ́ ọkàn mi lati ihò idibàjẹ wá: nitori iwọ ti gbe gbogbo ẹ̀ṣẹ mi si ẹ̀hin rẹ.
18Nitori ibojì kò le yìn ọ, ikú kò le fiyìn fun ọ: awọn ti o sọkalẹ lọ sinu ihò kò le ni irèti otitọ rẹ.
19Alãyè, alãyè, on ni yio yìn ọ, bi mo ti nṣe loni yi: baba yio fi otitọ rẹ hàn fun awọn ọmọ.
20Oluwa mura tan lati gbà mi: nitorina a o kọ orin mi lara dùrù olokùn, ni gbogbo ọjọ aiye wa ni ile Oluwa.
21Nitori Isaiah ti wipe, Ki nwọn mu ìṣu ọ̀pọtọ́, ki a si fi ṣán õwo na, yio si sàn.
22Hesekiah pẹlu ti wipe, Kili àmi na pe emi o goke lọ si ile Oluwa?

Àwon tá yàn lọ́wọ́lọ́wọ́ báyìí:

Isa 38: YBCV

Ìsàmì-sí

Pín

Daako

None

Ṣé o fẹ́ fi àwọn ohun pàtàkì pamọ́ sórí gbogbo àwọn ẹ̀rọ rẹ? Wọlé pẹ̀lú àkántì tuntun tàbí wọlé pẹ̀lú àkántì tí tẹ́lẹ̀

YouVersion nlo awọn kuki lati ṣe adani iriri rẹ. Nipa lilo oju opo wẹẹbu wa, o gba lilo awọn kuki wa gẹgẹbi a ti ṣalaye ninu Eto Afihan wa