SUNMỌ tosí, ẹnyin orilẹ-ède lati gbọ́, tẹtisilẹ ẹnyin enia, jẹ ki aiye gbọ́, ati ẹ̀kun rẹ̀; aiye ati ohun gbogbo ti o ti inu rẹ̀ jade. Nitori ibinu Oluwa mbẹ lara gbogbo orilẹ-ède, ati irúnu rẹ̀ lori gbogbo ogun wọn: o ti pa wọn run patapata, o ti fi wọn fun pipa. Awọn ti a pa ninu wọn li a o si jù sode, õrùn wọn yio ti inu okú wọn jade, awọn oke-nla yio si yọ́ nipa ẹ̀jẹ wọn. Gbogbo awọn ogun ọrun ni yio di yiyọ́, a o si ká awọn ọrun jọ bi takàda, gbogbo ogun wọn yio si ṣubu lulẹ, bi ewe ti ibọ́ kuro lara àjara, ati bi bibọ́ eso lara igi ọ̀pọtọ́. Nitori ti a rẹ́ idà mi li ọrun, kiyesi i, yio sọkalẹ wá sori Idumea, ati sori awọn enia egún mi, fun idajọ. Idà Oluwa kun fun ẹ̀jẹ, a mu u sanra fun ọ̀ra, ati fun ẹ̀jẹ ọdọ-agutan ati ewurẹ, fun ọrá erẽ àgbo: nitoriti Oluwa ni irubọ kan ni Bosra, ati ipakupa nla kan ni ilẹ Idumea. Ati awọn agbanrere yio bá wọn sọkalẹ wá, ati awọn ẹgbọ̀rọ malu pẹlu awọn akọ malu; ilẹ wọn li a o fi ẹ̀jẹ rin, a o si fi ọ̀rá sọ ekuru wọn di ọlọ́ra. Nitori ọjọ ẹsan Oluwa ni, ati ọdun isanpadà, nitori ọ̀ran Sioni.
Kà Isa 34
Feti si Isa 34
Pín
Fi gbogbo Èyá wéra: Isa 34:1-8
Ṣe àfipamọ́ àwọn ẹsẹ, kàá ní aìsìní orí ayélujára, wo àwọn àgékúrú ìkọ́ni, àti díẹ̀ síi!
Ilé
Bíbélì
Àwon ètò
Àwon Fídíò