Isa 32
32
Ọba tí ó ṣeé gbẹ́kẹ̀ lé
1KIYESI i, ọba kan yio jẹ li ododo, awọn olori yio fi idajọ ṣe akoso.
2Ẹnikan yio si jẹ bi ibi isápamọ́ kuro loju ẹfũfu, ati ãbo kuro lọwọ ijì; bi odo-omi ni ibi gbigbẹ, bi ojiji apata nla ni ilẹ gbigbẹ.
3Oju awọn ẹniti o riran kì yio ṣe baibai, ati eti awọn ti o ngbọ́ yio tẹ́ silẹ.
4Ọkàn awọn oniwàduwàdu yio mọ̀ oye, ahọn awọn akolòlo yio sọ̀rọ kedere.
5A kì yio tun pè alaigbọ́n ni ẹni-ọlá mọ, bẹ̃ni a kì yio pe ọ̀bàlújẹ́ ni ẹni pataki mọ.
6Nitori eniakenia yio ma sọ isọkusọ, ọkàn rẹ̀ yio si ma ṣiṣẹ aiṣedede, lati ṣe agabàgebe, ati lati ṣì ọ̀rọ sọ si Oluwa, lati sọ ọkàn ẹniti ebi npa di ofo, ati lati mu ki ohun-mimu awọn ti ongbẹ ngbẹ ki o dá.
7Ibi ni gbogbo ohun-elò enia-kenia jẹ pẹlu: on gbà èro buburu, lati fi ọ̀rọ eke pa talaka run, bi alaini tilẹ nsọ õtọ ọ̀rọ.
8Ṣugbọn ẹni-rere a ma gbèro ohun rere; nipa ohun-rere ni yio ṣe duro.
Ìdájọ́ ati Ìmúpadàbọ̀sípò
9Dide, ẹnyin obinrin ti o wà ni irọra; gbọ́ ohùn mi, ẹnyin alafara obinrin; fetisi ọ̀rọ mi.
10Ọpọlọpọ ọjọ, on ọdún, li a o fi ma wahala nyin, ẹnyin alafara obinrin: nitori ikore kì yio si, kikojọ rẹ̀ kì yio de.
11Warìri, ẹnyin obinrin ti o wà ni irọra; ki wahala ba nyin ẹnyin alafara: ẹ tú aṣọ, ki ẹ si wà ni ihòho, ki ẹ si dì àmure ẹgbẹ́ nyin.
12Nwọn o pohùnrere fun ọmú, fun pápa daradara, ati fun àjara eleso.
13Ẹgún ọ̀gan on òṣuṣu yio wá sori ilẹ awọn enia mi; nitõtọ, si gbogbo ile ayọ̀ ni ilu alayọ̀.
14Nitoripe a o kọ̀ ãfin wọnni silẹ; a o fi ilu ariwo na silẹ; odi ati ile-iṣọ́ ni yio di ihò titi lai, ayọ̀ fun kẹtẹkẹ́tẹ-igbẹ, pápa-oko fun ọwọ́-ẹran;
15Titi a o fi tú Ẹmi jade si wa lara lati oke wá, ati ti aginju yio fi di ilẹ eléso, ti a o si kà ilẹ eleso si bi igbo.
16Nigbana ni idajọ yio ma gbe aginju; ati ododo ninu ilẹ eleso.
17Iṣẹ ododo yio si jẹ alafia, ati eso ododo yio jẹ idakẹjẹ on ãbo titi lai.
18Awọn enia mi yio si ma gbe ibugbe alafia, ati ni ibugbe idaniloju, ati ni ibi isimi iparọrọ;
19Ṣugbọn yio rọ̀ yìnyín, nigbati igbó nṣubu lulẹ; ati ni irẹlẹ a o rẹ̀ ilu na silẹ.
20Alabukun fun ni ẹnyin ti nfọ̀nrugbìn niha omi gbogbo, ti nrán ẹṣẹ malu ati ti kẹtẹkẹtẹ jade sibẹ.
Àwon tá yàn lọ́wọ́lọ́wọ́ báyìí:
Isa 32: YBCV
Ìsàmì-sí
Pín
Daako
Ṣé o fẹ́ fi àwọn ohun pàtàkì pamọ́ sórí gbogbo àwọn ẹ̀rọ rẹ? Wọlé pẹ̀lú àkántì tuntun tàbí wọlé pẹ̀lú àkántì tí tẹ́lẹ̀
Yoruba Bible Crowther Version © The Bible Society of Nigeria, 2012.