Isa 3
3
Ìdàrúdàpọ̀ Ní Jerusalẹmu
1KIYESI i, Oluwa, Oluwa awọn ọmọ-ogun, mu idaduro ati ọpá kuro ninu Jerusalemu ati Juda, gbogbo idaduro onjẹ, ati gbogbo idaduro omi.
2Alagbara ọkunrin, ati jagunjagun, onidajọ, ati wolĩ, ati amoye, ati agbà.
3Balogun ãdọta, ati ọkunrin ọlọla, ati igbìmọ, ati oniṣọ̀na, ati alasọdùn.
4Awọn ọmọde li emi o fi ṣe ọmọ-alade wọn, awọn ọmọ-ọwọ ni yio si ma ṣe akoso wọn.
5A o si ni awọn enia lara, olukuluku lọwọ ẹnikeji, ati olukuluku lọwọ aladugbo rẹ̀; ọmọde yio huwà igberaga si àgba, ati alailọla si ọlọla.
6Nigbati enia kan yio di arakunrin rẹ̀ ti ile baba rẹ̀ mu, wipe, Iwọ ni aṣọ, mã ṣe alakoso wa, ki o si jẹ ki iparun yi wà labẹ ọwọ́ rẹ.
7Lọjọ na ni yio bura, wipe, Emi kì yio ṣe alatunṣe; nitori ni ile mi kò si onjẹ tabi aṣọ: máṣe fi emi ṣe alakoso awọn enia.
8Nitori Jerusalemu di iparun, Juda si ṣubu: nitori ahọn wọn ati iṣe wọn lòdi si Oluwa, lati mu oju ogo rẹ̀ binu.
9Iwò oju wọn njẹri si wọn; nwọn si nfi ẹ̀ṣẹ wọn hàn bi Sodomu, nwọn kò pa a mọ. Egbe ni fun ọkàn wọn! nitori nwọn ti fi ibi san a fun ara wọn.
10Ẹ sọ fun olododo pe, yio dara fun u: nitori nwọn o jẹ eso iṣe wọn.
11Egbe ni fun enia buburu! yio buru fun u: nitori ere ọwọ́ rẹ̀ li a o fi fun u.
12Niti awọn enia mi awọn ọmọde ni aninilara wọn, awọn obinrin si njọba wọn. A! enia mi, awọn ti nyẹ ọ si mu ọ ṣìna, nwọn si npa ipa-ọ̀na rẹ run.
OLUWA Dá Àwọn Eniyan Rẹ̀ Lẹ́jọ́
13Oluwa dide duro lati wijọ, o si dide lati da awọn enia li ẹjọ.
14Oluwa yio ba awọn agbà enia rẹ̀ lọ sinu idajọ, ati awọn ọmọ-alade inu wọn: nitori ẹnyin ti jẹ ọ̀gba àjara nì run: ẹrù awọn talakà mbẹ ninu ile nyin.
15Oluwa, Oluwa awọn ọmọ-ogun wipe, Kili ẹnyin rò ti ẹ fi fọ́ awọn enia mi tutu, ti ẹ si fi oju awọn talakà rinlẹ?
Ìkìlọ̀ fún Àwọn Obinrin Jerusalẹmu
16Pẹlupẹlu Oluwa wipe, Nitori awọn ọmọbinrin Sioni gberaga, ti nwọn si nrìn pẹlu ọrùn giga ati oju ifẹkufẹ, ti nwọn nrìn ti nwọn si nyan bi nwọn ti nlọ, ti nwọn si njẹ ki ẹsẹ wọn ró woro:
17Nitorina Oluwa yio fi ẽpá lu atàri awọn ọmọbinrin Sioni, Oluwa yio si fi ihoho wọn hàn.
18Li ọjọ na Oluwa yio mu ogo ṣaworo wọn kuro, ati awọn ọṣọ́ wọn, ati iweri wọn bi oṣupa.
19Ati ẹ̀wọn, ati jufù, ati ìboju,
20Ati akẹtẹ̀, ati ohun ọṣọ́-ẹsẹ, ati ọjá-ori, ati ago olõrùn didùn, ati oruka eti,
21Oruka, ati ọṣọ́-imu,
22Ipãrọ̀ aṣọ wiwọ, ati aṣọ ilekè, ati ibọ̀run, ati àpo,
23Awòjiji, ati aṣọ ọ̀gbọ daradara, ati ibòri ati ibòju,
24Yio si ṣe pe, õrun buburu yio wà dipò õrun didùn; akisà ni yio si dipò amùre; ori pipá ni yio si dipò irun didì daradara; sisan aṣọ ọ̀fọ dipò igbaiya, ijoná yio si dipò ẹwà.
25Awọn ọkunrin rẹ yio ti ipa idà ṣubu, ati awọn alagbara rẹ loju ogun.
26Awọn bodè rẹ̀ yio pohùnrere ẹkun, nwọn o si ṣọ̀fọ; ati on, nitori o di ahoro, yio joko ni ilẹ.
Àwon tá yàn lọ́wọ́lọ́wọ́ báyìí:
Isa 3: YBCV
Ìsàmì-sí
Pín
Daako
Ṣé o fẹ́ fi àwọn ohun pàtàkì pamọ́ sórí gbogbo àwọn ẹ̀rọ rẹ? Wọlé pẹ̀lú àkántì tuntun tàbí wọlé pẹ̀lú àkántì tí tẹ́lẹ̀
Yoruba Bible Crowther Version © The Bible Society of Nigeria, 2012.