Isa 16
16
Kò sí Ìrètí fún Moabu Mọ́
1Ẹ rán ọdọ-agutan si alakoso ilẹ lati Sela wá si aginju, si oke ọmọbinrin Sioni.
2Yio si ṣe, bi alarinkiri ẹiyẹ ti a le jade kuro ninu itẹ́-ẹiyẹ, bẹ̃ni ọmọbinrin Moabu yio ri ni iwọdò Arnoni.
3Ẹ gbìmọ, ẹ mu idajọ ṣẹ; ṣe ojiji rẹ bi oru li ãrin ọsángangan; pa awọn ti a le jade mọ́; máṣe fi isánsa hàn.
4Moabu, jẹ ki awọn isánsa mi ba ọ gbe, iwọ ma jẹ ãbo fun wọn li oju akoni: nitori alọnilọwọgbà de opin, akoni dasẹ̀, a pa awọn aninilara run kuro lori ilẹ.
5Ninu ãnu li a o si fi idi ilẹ mulẹ: yio si joko lori rẹ̀ li otitọ ninu agọ Dafidi, yio ma ṣe idajọ, yio si ma wá idajọ, yio si ma mu ododo yara kánkán.
6Awa ti gbọ́ ti igberaga Moabu; o gberaga pọju: ani ti irera rẹ̀, ati igberaga rẹ̀, ati ibinu rẹ̀; ihalẹ rẹ̀ asan ni.
7Nitorina ni Moabu yio hu fun Moabu, gbogbo wọn o hu: nitori ipilẹ Kir-haresi li ẹnyin o gbàwẹ; nitõtọ a lù wọn.
8Nitori igbẹ́ Heṣboni rọ, ati àjara Sibma: awọn oluwa awọn keferi ti ke pataki ọ̀gbin rẹ̀ lu ilẹ, nwọn tàn de Jaseri, nwọn nrìn kakiri aginjù: ẹka rẹ̀ nà jade, nwọn kọja okun.
9Nitorina emi o pohùnrére ẹkun, bi ẹkun Jaseri, àjara Sibma: emi o fi omije mi rin ọ, iwọ Heṣboni, ati Eleale: nitori ariwo nla ta lori èso-igi ẹ̃rùn rẹ, ati lori ikore rẹ.
10A si mu inu-didun kuro, ati ayọ̀ kuro ninu oko ti nso eso ọ̀pọlọpọ; orin kì yio si si mọ ninu ọgbà-àjara, bẹ̃ni kì yio si ihó-ayọ̀ mọ: afọnti kì yio fọn ọti-waini mọ ninu ifọnti wọn, emi ti mu ariwo dá.
11Nitorina inu mi yio dún bi harpu fun Moabu, ati ọkàn mi fun Kir-haresi.
12Yio si ṣe, nigbati a ba ri pe ãrẹ̀ mú Moabu ni ibi giga, ni yio wá si ibi-mimọ́ rẹ̀ lati gbadura; ṣugbọn kì yio bori.
13Eyi li ọ̀rọ ti Oluwa ti sọ niti Moabu lati igbà na wá.
14Ṣugbọn nisisiyi Oluwa ti sọ̀rọ, wipe, Niwọn ọdun mẹta, gẹgẹ bi ọdun alagbaṣe, a o si kẹgàn ogo Moabu, pẹlu gbogbo ọ̀pọlọpọ nì: awọn iyokù yio kere, kì yio si li agbara.
Àwon tá yàn lọ́wọ́lọ́wọ́ báyìí:
Isa 16: YBCV
Ìsàmì-sí
Pín
Daako
Ṣé o fẹ́ fi àwọn ohun pàtàkì pamọ́ sórí gbogbo àwọn ẹ̀rọ rẹ? Wọlé pẹ̀lú àkántì tuntun tàbí wọlé pẹ̀lú àkántì tí tẹ́lẹ̀
Yoruba Bible Crowther Version © The Bible Society of Nigeria, 2012.