Yio si ṣe li ọjọ na, iyokù Israeli, ati iru awọn ti o salà ni ile Jakobu, ki yio tun duro tì ẹniti o lù wọn mọ; ṣugbọn nwọn o duro tì Oluwa, Ẹni-Mimọ Israeli, li otitọ. Awọn iyokù yio pada, awọn iyokù ti Jakobu, si Ọlọrun alagbara. Bi Israeli enia rẹ ba dàbi iyanrìn okun, sibẹ iyokù ninu wọn o pada: aṣẹ iparun na yio kun àkúnwọ́sílẹ̀ ninu ododo. Nitori Oluwa, Oluwa awọn ọmọ-ogun yio ṣe iparun, ani ipinnu, li ãrin ilẹ gbogbo. Nitorina bayi li Oluwa, Oluwa awọn ọmọ-ogun wi, Ẹnyin enia mi ti ngbe Sioni, ẹ má bẹ̀ru awọn ara Assiria: on o fi ọgọ lù ọ, yio si gbe ọpa rẹ̀ soke si ọ, gẹgẹ bi iru ti Egipti. Ṣugbọn niwọn igba diẹ kiun, irunú yio si tan, ati ibinu mi ninu iparun wọn. Oluwa awọn ọmọ-ogun yio gbe paṣan kan soke fun u, gẹgẹ bi ipakupa ti Midiani ni apata Orebu: ati gẹgẹ bi ọgọ rẹ̀ soju okun, bẹ̃ni yio gbe e soke gẹgẹ bi iru ti Egipti. Yio si ṣe li ọjọ na, ni a o gbe ẹrù rẹ̀ kuro li ejika rẹ, ati àjaga rẹ̀ kuro li ọrùn rẹ, a o si ba àjaga na jẹ ní ọrùn rẹ.
Kà Isa 10
Feti si Isa 10
Pín
Fi gbogbo Èyá wéra: Isa 10:20-27
Ṣe àfipamọ́ àwọn ẹsẹ, kàá ní aìsìní orí ayélujára, wo àwọn àgékúrú ìkọ́ni, àti díẹ̀ síi!
Ilé
Bíbélì
Àwon ètò
Àwon Fídíò