Isa 10:1-3

Isa 10:1-3 YBCV

EGBE ni fun awọn ti npaṣẹ aiṣododo, ati fun awọn akọwe ti nkọ iwe ìka; Lati yi alaini kuro ni idajọ, ati lati mu ohun ẹtọ kuro lọwọ talakà enia mi, ki awọn opo ba le di ijẹ wọn, ati ki wọn ba le jà alainibaba li ole! Kili ẹnyin o ṣe lọjọ ibẹ̀wo, ati ni idahoro ti yio ti okere wá? tali ẹnyin o sá tọ̀ fun irànlọwọ? nibo li ẹnyin o si fi ogo nyin si?