Hos 3

3
Hosea ati Obinrin Alaiṣootọ
1OLUWA sí wi fun mi pe, Tun lọ, fẹ́ obinrin kan ti iṣe olùfẹ́ ọrẹ rẹ̀, ati panṣagà, gẹgẹ bi ifẹ Oluwa si awọn ọmọ Israeli, ti nwò awọn ọlọrun miràn, ti nwọn si nfẹ́ akàra eso àjara.
2Bẹ̃ni mo rà a fun ara mi ni fadakà mẹ̃dogun, ati homeri barli kan pẹlu ãbọ̀:
3Mo si wi fun u pe, Iwọ o ba mi gbe li ọjọ pupọ̀; iwọ kì yio si hùwa agbère, iwọ kì yio si jẹ ti ọkunrin miràn: bẹ̃li emi o jẹ tirẹ pẹlu.
4Nitori ọjọ pupọ̀ li awọn ọmọ Israeli yio gbe li aini ọba, ati li aini olori, ati li aini ẹbọ, li aini ere, ati li aini awòaiyà, ati li aini tẹrafimu.
5Lẹhìn na awọn ọmọ Israeli yio padà, nwọn o si wá Oluwa Ọlọrun wọn, ati Dafidi ọba wọn; nwọn o si bẹ̀ru Oluwa, ati ore rẹ̀ li ọjọ ikẹhìn.

Àwon tá yàn lọ́wọ́lọ́wọ́ báyìí:

Hos 3: YBCV

Ìsàmì-sí

Pín

Daako

None

Ṣé o fẹ́ fi àwọn ohun pàtàkì pamọ́ sórí gbogbo àwọn ẹ̀rọ rẹ? Wọlé pẹ̀lú àkántì tuntun tàbí wọlé pẹ̀lú àkántì tí tẹ́lẹ̀