Hos 10:12-13

Hos 10:12-13 YBCV

Ẹ furùngbin fun ara nyin li ododo, ẹ ká li ãnu: ẹ tú ilẹ nyin ti a kò ro: nitori o to akokò lati wá Oluwa, titi yio fi de, ti yio si fi rọ̀jo ododo si nyin. Ẹnyin ti tulẹ ìwa-buburu, ẹnyin ti ká aiṣedẽde; ẹnyin ti jẹ eso eke: nitori iwọ gbẹkẹ̀le ọ̀na rẹ, ninu ọ̀pọlọpọ awọn alagbara rẹ.