Heb 7:15-19

Heb 7:15-19 YBCV

O si tún han gbangba jù bẹ̃ lọ bi o ti jẹ pe alufa miran dide gẹgẹ bi Melkisedeki, Eyiti a kò fi jẹ gẹgẹ bi ofin ilana nipa ti ara, bikoṣe nipa agbara ti ìye ailopin. Nitori a jẹri pe, Iwọ ni alufa titi lai nipa ẹsẹ Melkisedeki. Nitori a mu ofin iṣaju kuro, nitori ailera ati ailere rẹ̀. (Nitori ofin kò mu ohunkohun pé), a si mu ireti ti o dara jù wá nipa eyiti awa nsunmọ Ọlọrun.