Heb 7:11-28

Heb 7:11-28 YBCV

Njẹ ibaṣepe pipé mbẹ nipa oyè alufa Lefi, (nitoripe labẹ rẹ̀ li awọn enia gbà ofin), kili o si tún kù mọ́ ti alufa miran iba fi dide nipa ẹsẹ Melkisedeki, ti a kò si wipe nipa ẹsẹ Aaroni? Nitoripe bi a ti pàrọ oyè alufa, a kò si le ṣai pàrọ ofin. Nitori ẹniti a nsọ̀rọ nkan wọnyi nipa rẹ̀ jẹ ẹ̀ya miran, lati inu eyiti ẹnikẹni koi jọsin ri nibi pẹpẹ. Nitori o han gbangba pe lati inu ẹ̀ya Juda ni Oluwa wa ti dide; nipa ẹ̀ya ti Mose kò sọ ohunkohun niti awọn alufa. O si tún han gbangba jù bẹ̃ lọ bi o ti jẹ pe alufa miran dide gẹgẹ bi Melkisedeki, Eyiti a kò fi jẹ gẹgẹ bi ofin ilana nipa ti ara, bikoṣe nipa agbara ti ìye ailopin. Nitori a jẹri pe, Iwọ ni alufa titi lai nipa ẹsẹ Melkisedeki. Nitori a mu ofin iṣaju kuro, nitori ailera ati ailere rẹ̀. (Nitori ofin kò mu ohunkohun pé), a si mu ireti ti o dara jù wá nipa eyiti awa nsunmọ Ọlọrun. Niwọn bi o si ti ṣe pe kì iṣe li aibura ni. (Nitori a ti fi wọn jẹ alufa laisi ibura, nipa ẹniti o wi fun u pe, Oluwa bura, kì yio si ronupiwada, Iwọ ni alufa kan titi lai nipa ẹsẹ Melkisedeki:) Niwọn bẹ̃ ni Jesu ti di onigbọ̀wọ́ majẹmu ti o dara jù. Ati nitõtọ awọn pupọ̀ li a ti fi jẹ alufa, nitori nwọn kò le wà titi nitori ikú: Ṣugbọn on, nitoriti o wà titi lai, o ni oyè alufa ti a kò le rọ̀ nipò. Nitorina o si le gba wọn là pẹlu titi de opin, ẹniti o ba tọ̀ Ọlọrun wá nipasẹ rẹ̀, nitoriti o mbẹ lãye titi lai lati mã bẹ̀bẹ fun wọn. Nitoripe irú Olori Alufa bẹ̃ li o yẹ wa, mimọ́, ailẹgan, ailẽri, ti a yà si ọ̀tọ kuro ninu ẹlẹṣẹ, ti a si gbéga jù awọn ọrun lọ; Ẹniti kò ni lati mã kọ́ rubọ lojojumọ, bi awọn olori alufa wọnni, fun ẹ̀ṣẹ ti ara rẹ̀ na, ati lẹhinna fun ti awọn enia: nitori eyi li o ti ṣe lẹ̃kanṣoṣo, nigbati o fi ara rẹ̀ rubọ. Nitoripe ofin a mã fi awọn enia ti o ni ailera jẹ olori alufa; ṣugbọn ọ̀rọ ti ibura, ti a ṣe lẹhin ofin, o fi Ọmọ jẹ, ẹniti a sọ di pipé titi lai.