Heb 5:5-11

Heb 5:5-11 YBCV

Bẹ̃ni Kristi pẹlu kò si ṣe ara rẹ̀ logo lati jẹ́ Olori Alufa; bikoṣe ẹniti o wi fun u pe, Iwọ li Ọmọ mi, loni ni mo bí ọ. Bi o ti wi pẹlu nibomiran pe, Iwọ ni alufa titi lai nipa ẹsẹ Melkisedeki. Ẹni nigba ọjọ rẹ̀ ninu ara, ti o fi ẹkún rara ati omije gbadura, ti o si bẹ̀bẹ lọdọ ẹniti o le gbà a silẹ lọwọ ikú, a si gbohun rẹ̀ nitori ẹmi ọ̀wọ rẹ̀, Bi o ti jẹ Ọmọ nì, sibẹ o kọ́ igbọran nipa ohun ti o jìya; Bi a si ti sọ ọ di pipé, o wá di orisun igbala ainipẹkun fun gbogbo awọn ti o ngbọ́ tirẹ̀: Ti a yàn li Olori Alufa lati ọdọ Ọlọrun wá nipa ẹsẹ Melkisedeki. Niti ẹniti awa ni ohun pupọ̀ lati sọ, ti o si ṣoro lati tumọ, nitoripe ẹ yigbì ni gbigbọ́.