Nitoripe awa kò ni ilu ti o wà titi nihin, ṣugbọn awa nwá eyiti mbọ̀. Njẹ nipasẹ rẹ̀, ẹ jẹ ki a mã ru ẹbọ iyìn si Ọlọrun nigbagbogbo, eyini ni eso ète wa, ti njẹwọ orukọ rẹ̀. Ṣugbọn ati mã ṣõre on ati mã pinfunni ẹ máṣe gbagbé: nitori irú ẹbọ wọnni ni inu Ọlọrun dùn si jọjọ. Ẹ mã gbọ ti awọn ti nṣe olori nyin, ki ẹ si mã tẹriba fun wọn: nitori nwọn nṣọ ẹṣọ nitori ọkàn nyin, bi awọn ti yio ṣe iṣíro, ki nwọn ki o le fi ayọ̀ ṣe eyi, li aisi ibinujẹ, nitori eyiyi yio jẹ ailere fun nyin. Ẹ mã gbadura fun wa: nitori awa gbagbọ pe awa ni ẹri-ọkàn rere, a si nfẹ lati mã wà lododo ninu ohun gbogbo. Ṣugbọn emi mbẹ̀ nyin gidigidi si i lati mã ṣe eyi, ki a ba le tète fi mi fun nyin pada. Njẹ Ọlọrun alafia, ẹniti o tun mu oluṣọ-agutan nla ti awọn agutan, ti inu okú wá, nipa ẹ̀jẹ majẹmu aiyeraiye, ani Oluwa wa Jesu, Ki o mu nyin pé ninu iṣẹ rere gbogbo lati ṣe ifẹ rẹ̀, ki o mã ṣiṣẹ ohun ti iṣe itẹwọgba niwaju rẹ̀ ninu wa nipasẹ Jesu Kristi; ẹniti ogo wà fun lai ati lailai. Amin.
Kà Heb 13
Feti si Heb 13
Pín
Fi gbogbo Èyá wéra: Heb 13:14-21
Ṣe àfipamọ́ àwọn ẹsẹ, kàá ní aìsìní orí ayélujára, wo àwọn àgékúrú ìkọ́ni, àti díẹ̀ síi!
Ilé
Bíbélì
Àwon ètò
Àwon Fídíò