Hag 2:10-14

Hag 2:10-14 YBCV

Li ọjọ ikẹrinlelogun oṣù kẹsan, li ọdun keji Dariusi, li ọ̀rọ Oluwa wá nipa Hagai woli, pe, Bayi li Oluwa awọn ọmọ-ogun wi; bère ofin lọwọ awọn alufa nisisiyi, pe, Bi ẹnikan ba rù ẹran mimọ́ ni iṣẹti aṣọ rẹ̀, ti o si fi iṣẹti aṣọ rẹ̀ kan àkara, tabi àṣaró, tabi ọti-waini, tabi ororo, tabi ẹrankẹran, yio ha jẹ mimọ́? Awọn alufa si dahùn wipe, Bẹ̃kọ. Hagai si wipe, Bi ẹnikan ti o ba jẹ alaimọ́ nipa okú ba fi ara kan ọkan ninu wọnyi, yio ha jẹ alaimọ́? Awọn alufa si dahùn wipe, Yio jẹ alaimọ́. Nigbana ni Hagai dahùn o si wipe, Bẹ̃ni enia wọnyi ri, bẹ̃ si ni orilẹ-ède yi ri niwaju mi, li Oluwa wi; bẹ̃ si li olukuluku iṣẹ ọwọ wọn; eyiti nwọn si fi rubọ nibẹ̀ jẹ alaimọ́.