Egbe ni fun ẹniti o fi ohun mimu fun aladugbo rẹ̀, ti o si fi ọti-lile rẹ fun u, ti o si jẹ ki o mu amupara pẹlu, ki iwọ ba le wò ihòho wọn! Itìju bò ọ nipò ogo, iwọ mu pẹlu, ki abẹ́ rẹ le hàn, ago ọwọ́ ọtun Oluwa ni a o yipadà si ọ, ati itọ́ itìju sára ogo rẹ. Nitori ti ìwa-ipá ti Lebanoni yio bò ọ, ati ikogun awọn ẹranko, ti o bà wọn li ẹ̀ru, nitori ẹjẹ̀ enia, ati ìwa ipá ilẹ na, ti ilu na, ati ti gbogbo awọn ti ngbe inu rẹ̀. Erè kini ere fínfin nì, ti oniṣọna rẹ̀ fi gbẹ́ ẹ; ere didà, ati olùkọ eké, ti ẹniti nṣe iṣẹ rẹ̀ fi gbẹkẹ̀le e, lati ma ṣe ere ti o yadi? Egbe ni fun ẹniti o wi fun igi pe, Ji; fun okuta ti o yadi pe, Dide, on o kọ́ ni! Kiyesi i, wurà ati fàdakà li a fi bò o yika, kò si si ẽmi kan ninu rẹ̀. Ṣugbọn Oluwa mbẹ ninu tempili rẹ̀ mimọ́; jẹ ki gbogbo aiye pa rọ́rọ niwaju rẹ̀.
Kà Hab 2
Feti si Hab 2
Pín
Fi gbogbo Èyá wéra: Hab 2:15-20
Ṣe àfipamọ́ àwọn ẹsẹ, kàá ní aìsìní orí ayélujára, wo àwọn àgékúrú ìkọ́ni, àti díẹ̀ síi!
Ilé
Bíbélì
Àwon ètò
Àwon Fídíò